Ajo alaabo sifu lorileede yii ti
kilo fawon osise abe won lati gbakiyesi ara nipa iforukosile to n lo lori ero
ayelujara fawon to fee gbase naa, nitori eni tawon ba gbo pe o gbowo tabi so pe
kawon to n wase naa loo mowo wa yoo kandi ninu iyo.
Ninu atejade ti Ogbeni Ekunola
Gbenga, fi sita loruko oga agba patapata fajo naa lati ilu Abuja lo ti so pe
ofe ni eto naa wa fun gbogbo awon to nifee lati gbase naa.
O wa ro awon araalu paapaa awon to
fee gbase naa lati ma se ba enikeni dowopo gege bi oniduro fun rto igbanisise
to n lo lowo naa.
O te siwaju pe ajo naa ti n sise
labele lati sawari awon oniwa ibaje ti won fee maa se nnkan ti ko bojumu naa.
Ekunola tun fi kun oro e pe awon gbo
pe awon oniwa ibaje kan ti bere si fee maa gbowo lowo awon to n foruko sile naa
ti won si n mu dawon loju pe awon yoo se oniduro fun won ti won yoo fi gbase
naa.
O wa pari oro e pe eto to n lo lowo
naa ko nii se pelu owo kankan, nitori idi eyi ko seni kankan ti won so fun pe ko
lo sanwo si banki fun eto naa.
No comments:
Post a Comment