Onarebu Olakunle Oluomo, to je olori ile igbimo asofin nipinle Ogun ti
gbosuba o kare fajo alaabo ilu sifu ati egbe awon olopaa agbegbe iyen PCRC fun
bi won sise takuntakun lati dabobo emi awon araalu ati nnkan ini won.
Okunrin naa soro yii lakooko to n gba alejo oga agba fajo sifu nipinle
Ogun, Hamid Abodunrin ati alaga PCRC, Pasito Adebayo Lawson ni ofisi e.
Oluomo so pe ipa kekere ko ni awon mejeeji ti ko lati ri pe alafia ati
ilosiwaju nipinle yii lati gba ti won ti se idasile won.
Ko to di pe olori ile igbimo asofin
naa soro ni oga agba fajo sifu, Ogbeni loun naa ti gboriyin fun ile igbimo
asofin fawon abadofin ti won ti se lori eto abo ati fun idagbasoke ipinle naa,
o wa seleri pe ajo alaabo sifu ko ni rewesi ninu ise lati pese eto abo to peye
fawon eeyan.
Ninu oro ti alaga fegbe PCRC nipinle Ogun,Pasito
Lawson so pe pelu idunnu loun fi
so pe igbimo oun lawon omo egbe to le ni egberun lona igba kaakiri ipinle Ogun,
O ni ti won si fara won sile fun eto abo agbegbe won.
O wa lo akoko naa lati dupe lowo ile
igbimo asofin nipa bi won se gba abadofin egbe alaabo 'So Safe Corps' wole ,
eyi to ni o mu kawon fijilante ipinle Ogun di egbe tuntun naa, eyi to tubo je
ki eto abo tun fi gberu si nipinle naa.
No comments:
Post a Comment