Gomina Dapo Abiodun tipinle Ogun ti
se ifilole igbimo ti yoo maa ri si owo iranwo eto abo, eyi to waye lojo
Abameta, Satide, ose to koja ni ofiisi gomina to wa niluu Abeokuta.
Nibe lo tun ti se ikilo leekan si pe
gbogbo awon onile to ba gba awon odaran sile ni won yoo rii pe won wo ile naa
lule, ti won yoo si gba iwe ile emi mo nile lowo onitohun.
Awon igbimo to sagbekale won ninu
eyi ti Ogbeni Bolaji Balogun, igbakeji
oga agba fawon olopaa, to ti feyin, ti
je alaga won ni, bee ni a tun ti ri Olushola Subair Kamar, to je oga leka isuna ni banki Access.
Awon yooku ni Seyi Kumapayi, Seyi Oyefeso,
Wole Akinleye, nigba Ogbeni Opeyemi Agbaje yoo si je akowe igbimo naa.
Omooba Dapo Abiodun tun wa so pe
gbogbo ile ti won ba ti rawon ajinigbe naa ni yoo di erupe patapata, ti ko si
ni gberi mo.
O tun mu dawon igbimo owo iranwo eto
abo naa loju pe gbogbo ohun to nii se
pelu dukia awon eeyan naa ni abo to peye yoo wa fun.
Bee lo tun so lojo naa pe inu oun
dun pe oun tun mu ileri oun se lori ona lati pese isakoso rere fawon eeyan
ipinle naa. O ni o da loun loju pe ipinle Ogun ko nii je ile awon odaran mo.
Gomina wa lo akoko naa lati ke si
awon oba alaye, awon eeyan agbegbe oni dagbasoke, elegbejegbe awon onisowo
lawujo lati fowosowopo pelu ijoba ki won le gbogun tawon odaran naa.
Bee lo tun akoko naa lati so fawon
ti ko nise lowo lati lo anfaani ipese ise to wa nita lati kopa fun ise tijoba
fee gbawon eeyan si. O ni oun nigbagbo pe pelu igbimo ti won sefilole e yii,
abo yoo tubo lagbara si lawujo tawon eeyan n gbe ati dukia won.
Ninu oro e, Ogbeni Bolaji Balogun,
to je alaga naa yoo se sise takuntakun, won ko si nii doju ti awon omo ipinle
Ogun, o ni won yoo sise naa, bo se to ati bo se ye.
O sapejuwe Gomina Dapo Abiodun gege
bi eni ti ko foro abo ipinle e sere, o ni eni ti iwe itan ko nii gbagbe ni, o
lo wa se gomina lakooko to dara.
No comments:
Post a Comment