Egbe oselu lapapo ti won foruko sile
nipinle Ogun, iyen The League of Registered Political Parties eyi ti Oginni
Olaposi, Otunba Adebayo Mosuro ati Alaaji Moshood Adesina saaju fun ti gba
ileejo lo lojobo, Tosidee, to koja lati so pe awon naa loro so nileejo niwaju
igbimo to n gbejo lori idibo gomina to waye lodun yii, ti Adajo Halilu atawon adajo meji yooku n gbo
lowo.
Bo tile je pe won ni iru nnkan bee
ko ti sele ri, sugbon awon gbe igbese naa lati rii pe awon darapo mo iko ti
Dapo Abiodun ninu igbejo to n loo lowo naa.
Okan lara won to ba oniroyin wa soro
so pe niwongba ti gbogbo awon egbe oselu ti won foruko sile naa ti koko ro
Onarebu Akinlade to je oludije labe egbe
oselu APM pe ko jawo ninu ejo to pe Gomina Dapo Abiodun lori ibo gomina to waye
naa, ki nnkan si maa lo bo se ye, to ko jale pe oun ko jawo lawon naa se pinnu
lati gbe igbese naa.
O fikun
oro e pelu awon eri tawon naa ni lowo fi han gbangba pe ibo naa loo bo se ye ko loo ti ko si wahala kankan ninu e, won ni
awon oludije gomina yooku ati apapo egbe oselu lawon nigbagbo ninu ipinnu ti
igbimo yoo gba won lati je alabapin ninu
igbejo naa.
Iwe ipejo lati gbe leyin Dapo
Abiodun ninu igbejo naa la gbon pe Otunba
Adebayo Atanda Mosuro tinu egbe oselu Independent Democrats fi sits loruko awon oludije gomina egbe oselu
yooku ti won dije ninu ibo 2019.
Bee la gbo
pe gbogbo ibi tejo naa ba n lo bayii ni won setan pe awon yoo maa tele won lo
tawon si ti ni agbejoro ti won bayii.
No comments:
Post a Comment