Oba Fatai
Akorede Akamo, Olu tilu Itori, ti so pe pataki ni igbega asa ile Yoruba je
foun, idi niyii toun fi maa n karamasiki e ni gbogbo igba, nitori pe igbagbo
oun ni pe ko gbodo pare.
Oba naa soro
yii lakooko tegbe to n ri si iranti
awon alawo dudu to ku sodo lakooko owo eru ati asa iyen African Diaspora
Ancestral Clommemoration Institute, ADACI, n fi oba naa je Baba isale won.
Ayeye naa
to waye ni afin Olu- Itori, ni alakoso egbe naa ni orileede yii, Iyaafin Laide Gold ti saaju awon omo egbe e yooku lo
fami eye da Oba naa lola, ti won si tun fun un niwe eri pelu.
Kabiyesi
naa so pe nnkan akoko toun fee kawon omo egbe ADACI naa ni ooto, ki won fi bara
won lo, nitori ooto lo n gbe orileede leke.
Bee lo tun
so pe latile ninu eje oun ni igbelaruge asa wa, idi niyii to fi je pe ko sibi
ti won ba ti n se iru nnkan bee, toun ki i yoju, bo tile je inu erofo loun ti
jade wa sugbon oun dupe fun ipo ti oun ba ara oun loni yii.
O wa ro awon omo egbe naa lati ma se rewesi
tabi kaare lori ise to wa niwaju won, ki won si je ki ife to jinle wa laarin
won.
Nibi ayeye
naa lo ti seleri pe oun yoo fun egbe naa ni piloti ile kan lati ko oluulese won
si ni Nigeria gege bi won se beere fun.
Nigba ti
Alakoso egbe naa, Iyaafin Laide Gold, koko dupe lowo Oba Akamo fun bo se gbawon
lalejo lojo naa bee lo so nipa idasile egbe naa atawon aseyori ti won ti se
latigba ti won ti da sile.
O so pe Oloye Fakunle Oyesanya ni aare egbe ADACI lorileede yii nigba ti Ogbeni Oga Joseph Bolanle si je akowe e, o fi kun un pe ADACI quest troupe je onijo to wa labe ADACI ti orileede yii.
Bee ni Obinrin naa tun so idi to fi je pe Olu Itori ni won mu lati fi se baba isale egbe naa, o ni Oba naa je eni to ko eeyan mora, to si je eni to nife
Bee ni Obinrin naa tun so idi to fi je pe Olu Itori ni won mu lati fi se baba isale egbe naa, o ni Oba naa je eni to ko eeyan mora, to si je eni to nife
Oluwakoya,Omolara Bakare,
Omooba-binrin Adeola Olaleye Micheal, Ogbeni Adesina Sanusi, Gbenga Oladipupo,
Muyideen Jonto atawon onio e pelu Ogbeni Johnson Akinpelu.
No comments:
Post a Comment