-Bee egberun marun un lo ti foruko
sile fun ti eto yawo ogbin.
Bo tile je pe ko tii ju ose kan lo
ti eto yawo fogbin si sile fun iforukosile lori ero ayelujara, o ti le ni
egberun marun un awon to nifee ti won ti foruko sile labe eto naa. Pambari e ni
pe igbase ogun ti won si sile naa tun ti wa fawon obinrin fun ironilagbara,
lati ya won lowo lati fi sowo eyi
won pe ni ‘Okowo Dapo’
Oludamoran gominan lori eto idasesile
ati ipse ise sile fawon odo, Ogbeni Lekan Olude, lo soro yii lojo Isegun, Tusidee, o tun fi kun
oro e pe ileese nla bi ogorun un to fee gba eeyan sise lo ti gbe iwase sori
igbase naa ti awon eto ayewo si ti bere loju ese.
O so ninu oro e pe titi di akoko
yii, awon bii egberun lona ogorun un lo ti foruko sile fun eto igbase to n lo
lowo sugbon egberun marun un lo ti foruko sile fun ti eto ogbin labe eto eyawo.
O fikun oro e pe opo awon ti won ba
saseyege ni won yoo seto anfaani ohun gbogbo ogbin fun un bi ile ti won yoo maa
dako si lofe, pelu iwe emi ni mo nile mi, awon ohun ogbin lorisirisi, bee ni
won yoo tun maa gbawo dakomu nibe pelu.
Olude tun fi kun oro e pe awon tawon
fee gba fun ti ogbin yii yoo fee to egberun lona ogoji sugbon oun gbawon
niyanju lati loo foruko sile lori ero ayelujara.
O tun muu dawon to ba forukosile
loju pe ko ni saye lati fidi enikeni remi fun ise naa niwongba ti won ba ti
koju osuwon ti won si lawon nnkan ti won beere fun lori ero ayelujara naa.
O ni iro patapata lawon to n gbe
aheso kaakiri pe awon to wa lati Abeokuta ati Ijebu nikan ni won fee gba si
ise, o ni ko si ooto kankan nibe, nitori pe gbogbo ipinle Ogun ni yoo janfaani eto to n
loo lowo naa to fi mo Yewa, Ota tabi Remo, gbogbo won lo so pe o wa fun.
O wa pari oro e pe ogorun un awon
ileese nla ni won ti gbe iwase won sabe igbanisise Ogun to n lo lowo, o ni awon
ti won ba ti pe ki won ya tete loo fun iforowanilenuwo pelu awon iwe eri ti won
ni lowo.
No comments:
Post a Comment