Dapo Abiodun yoo mu idagbasoke ba ipinle Ogun- Olumide - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 4 September 2019

Dapo Abiodun yoo mu idagbasoke ba ipinle Ogun- Olumide
Onimo-ero  Olumide Damilare, okan lara awon oludije fun ipo alaga ijoba ibile fun Abeokuta South  ti mu da gbogbo awon eeyan loju pe kekere ni nnkan ti won si n ri ninu ohun ti Gomina Dapo Abiodun tipinle Ogun, se lati mu idagbasoke ba ipinle naa, o ni okunrin naa sese mu eye bo lapo ni, nitori gbogbo awon araalu lo maa janfaani e.

 Okunrin naa soro yii lakooko to n bawon oniroyin soro, o so pe nnkan to daniloju ni pe iyalenu ni yoo je fawon araalu nigba tawon nnkan idagbasoke naa ba bere si nii wole.

O ni  bo tile je pe lakooko yii, ohun ti Gomina si n se ni lati yan awon eeyan ti won lebun, ti Olorun si fopolo jinki lati baa sise po ni eyi ti yoo mu ki ipinle naa tubo goke agba.

Olumide wa ro awon eeyan lati ma se pe okunrin naa ni Baba to n faseyin iyen 'baba go slow',  ninu ipadabo Abija loro okunrin naa nipa awon ohun imayederun.

O ni kawon eeyan ma se lo ogorun un akoko gomina lori isakoso e lati fi sejoba e nipa bijoba se n lo.O ni akoko ojo naa kii se nnkan tawon eeyan fi le maa woye bi gomina se sise si.

O ni oun to da oun loju nip e Gomina Dapo ko faseyin rara bi ko se pe o farabale lati wo awon nnkan to ti w anile ati ibi ti ise yoo ti bere, eyi to ni o si ti n se.

Lori erongba e lati di alaga ijoba ibile Abeokuta South, Okunrin naa so pe oun gbero lati tubo mu idagbasoke ba ijoba naa toun ba de be

O ni erongba Gomina Abodun to ni e je ka jot un ojo iwaju wa se papo loun naa yoo tele, lati fi ran awon eeyan to n gbe labe ijoba ibile naa lowo.

O nib o tile je pea won eeyan mo oun daadaa nidii oselu nijoba ibile Abeokuta South, o  ni oun ni erongba lati mu ayipada ba ijoba ibile naa.

O ni looto lawon to ti je alaga naa naa ti sa ipa won sibe oun naa yoo tun se toun lara oto.

No comments:

Post a Comment

Pages