Gomina Dapo Abiodun ti se se ileri pe isakoso ijoba oun yoo pese awon ohun elo lawon
ile iwosan titi de awon woodu kaakiri ipinle Ogun.
Gomina seleri yii lakooko to n se ifilole eto ilera,
eyi to waye ni Ilisan, nijoba ibile Ikenne, O so pe
eto ilera je eyi to je isakoso
oun logun julo nibi tawon araalu yoo ti maa ri itoju to peye gba.
O ni awon yoo rip e awon pese ohun
elo ilera sawon osibitu ijoba to sunmo awon araalu to wa ni agbegbe won. O ni awon
ile iwosan yii ni lo ye kawon araalu koko lo lati gba itoju ayafi eyi tagbara
won ko ba kaa ni won le gbe loo sawon ilewosan to pele ju won lo.
Abiodun fi kun oro e pe atunse ti n
loo lowo lori osibitu ijoba to wa ni Ilaro ati pe gbogbo awon ohun elo igbalode
lawon yoo ko sibe bi won ba ti pari ise naa. Bee naa lo ni ise si n loo lowo
lawon osibitu yooku to wa nipinle naa.
O ni bawon se nawo atunse sawon
osibitu naa lo mu kise maa loo lowo ni osibitu jenera yunifasiti Olabisi
Onabanjo (OOUTH), to wa niluu Sagamu, Tawon fee ko ba ti osibitu yunifasiti tiluu Eko iyenl (LUTH)
kegbe po
Abiodun lawon n reti esi abo igbimo
tawon gbe kale lori oro osibitu naa lati wa jabo fun won. Tawon yoo si
sagbeyewo abo esi naa ko to di pe awon fowo sii, ti yoo si di mimulo.
Lara awon to tun soro nibi eto to
waye naa ni akowe agba nileese to n ri si eto ilera, Dokita Efundayo Ayinde, so pee to ayewo ti won
se lowo naa yoo wa ayewo oju ati ara lofe ni gbogbo ipinle yii.
No comments:
Post a Comment