Gomina Dapo Abiodun tipinle Ogun, lo tun ti muu dawon eeyan ipinle Ogun loju pe gbogbo awon akanse ise to nii se pelu oro aje tijoba to kogba sile ko pari loun yoo rii pe ijoba toun pari e, ti yoo si di mimulo fawon araalu.
Lojobo, Tosidee, lo soro yii lakooko to n se ile ikekoo ti won
yoo ti maa ko nipa ero igbalode eyi ti won pe ni Ogun TechHUB, to waye lona
Kobape, niluu Abeokuta.
O ni nijoba oun ko ni laju sile lati
pa awon ise akanse ti won fowo araalu se ti, toun si mo pe yoo wulo fawon
araalu.
Dapo Abiodun tun so pe "Mo fee
lo akoko yii lati mu da awon eeyan loju pe a ko pa awon ise akanse to wulo
fawon araalu ti. Nitori pe owo awon araalu ni won fi se, a o rii pe gbogbo e la
pari nitori a ko nifee si bi ba nnkan je ".
O tun so pe ibi ti won sese si naa
tun fun isakoso oun lagbara lati yanju awon ohun elo ero igbalode lati le je ki
ipinle yii se dunnun wo, eyi ti yoo maa yanju isoro awon eeyan.
Abiodun tun mu dawon eeyan loju lojo
naa pe iru nnkan ti won si lojo naa lawon yoo tun se sawon ekun meji yooku to
wa nipinle Ogun.
O wa lo akoko naa lati pe awon eeyan paapaa
julo awon odo
lati lo afaaani eto ti won se
naa.Bee lo wa pe awon onile-ise nla atawon olokoowo lati sise po pelu ijoba ki
erongba won lori ise naa le yori si rere.
Ninu oro Dayo Abiodun, to je
oludamoran pataki lori eto iroyin igbalode, o so pe ibudo naa yoo wa fun ibi ti
awon elero igbalode, ijoba, olokoowo atawon mii in nipinle Ogun yoo ti maa lo
eto iroyin lona igbalode lati wa ojutu sawon isoro nile Naijiria.
Bakan naa ni Ojogbon Adesi Sodiya,
to je aare egbe komputa lorileede yii naa so pe ibudo naa yoo ran awon ti
Olorun fopolo jinki lati lo o fun idagbasoke.
No comments:
Post a Comment