Lara erongba lati le ri pe akanse
ise kekekee bere nipinle Ogun pelu ajosepo banki lagbaye, won ti se idanilekoo
olojo kan fawon osise ti won wa nileese,eka to wa labe ijoba ibile mefa lori eka
idagbasoke agbegbe.
Idanilekoo naa to waye ti won pe
akole e ni ipa ileese, eka ijoba to wa nipinle, ati aseyori erongba awon osise
naa. Onimo-ero
Sakirudeen Salaam, to je oga agba
fun CSDP so pe eto to waye naa yoo ran awon osise ijoba lowo lati koju osuwon
lori ise akanse lawon agbegbe won ati ipinle lapapo.
O fi kun oro e pe lara idagbasoke to
tun wa nibe ni lati yanju okoowo agbegbe lona ti yoo fi ran awon eeyan lowo
nipase isuna akanse okoowo kekekee lawon igberiko.
O ni ohun ti ajo CSDP wa fun ni lati ran awon eeyan agbegbe lowo,
lati fi tun igbesi aye won se nipase okoowo kekeke lawon igberiko.
Salaam salaye pe awon ise akanse naa
nii se pelu omi, buloku yara ikekoo, ilera, ona, koto atawon nnkan mii in lawon
sa tewogba lowo awon agbegbe to n se e.
Okunrin naa tun fidi e mule pe idi
tawon se pe awon akosemose paapaa awon
osise nileese ati eka ijoba iyen MDAs, si eto naa ni lati fun won ni oore ofe
lati lo opolo won ti won ti ni ninu ise fun erongba ijoba ipinle lati le mu ki
igbe aye awon eeysan nitumo si won, nipase ipese imayederun fawon eeyan agbegbe
to wa nigberiko lona ti owo ti won ba na nipase iforiti lori okoowo kekeeke ti
yoo ba banki lagbaye dogba.
Ninu oro ikini kaabo alaga igbimo
elekajeka, Oladipo Odeyemi, so pe idanileko
naa yoo je ki awon olukopa mo ipa ati ajosepo won pelu CSDP.
O fikun oro e pe idanilekoo naa yoo
tun je kawon akopa mo nipa ona ti won le gba tele awon ilana to ro mo eto naa
bee lo wa gbawon osise naa nimoran lati rise naa gege ipenija ki won si sa fun
awon nnkan to le bawon loruko je.
No comments:
Post a Comment