Lati le je ki eto abo araalu tun gun rege,Gomina Dapo Abiodun tipinle Ogun, ti fawon olopaa ni ogorun un moto ati igba okada, nibi ayeye kan to waye ni ofiisi gomina,Oke- Mosan, niluu Abeokuta.
Oga agba
patapata fawon olopaa lorileede yii, Mohammed Adamu ni Gomina fa moto ati okada
naa le lowo leyin to se ifilole e tan.
Nibe lo ti
kan sara si oga agba agba awon olopaa naa fun akitiyan e
lori eto abo kaakiri
orileede yii.Paapaa lori bi iwa ijinigbe, egbe okunkun atawon iwa odaran mii in
se dinku yato si bo se n sele laarin ojo ketalelogun si kerinlelogun, osu keje,
ati ni ojo kin in ni osu kejo,ti gbogbo e si ti n lole bayii.
Abiodun salaye pe oko ofurufu elikopita ti
won gbe sile lati fi sawari awon ti won ji gbe ran ipinle yii lowo lati bo ninu
isoro awon ajinigbe naa.
Gomina tun fidi e mule pe ko si ipinle naa
lorileede yii yo bo lowo esun odaran okan-o- jokan to waye naa ati pe agbekale igbimo ti yoo seto owo feto abo tawon
sagbekale, ti isakoso se abadofin lati gbe dide, nitori idi eyi owo yoo tete maa wa nile fun
ipese abo awon araalu.
Ninu oro ti oga agba patapata fawon olopaa
lorileede yii, Mohammed Adamu so pe wiwa toun wa ni lati tun ro awon olopaa abe
lagbara, lati gbe emo igboya wo won lati te siwaju nipa eto abo, o ni ijoba
apapo sa ipa won lopo igba nipa riro ileese olopaa lagbara nipa awon ohun elo.
Okunrin naa tun so pe ijoba apapo sakiyesi
pe ileese olopaa ni isoro aini ohun elo ija to, idi niyii to fi ni won gbe
igbese lati ra ati bo ti ye.
Adamu
wa fikun oro o pe awon olopaa ti setan
lati bere igbese olopaa agbegbe kaakiri orileede yii, o ni igba ti akoko lati
maa gba eeyan ba to, oun yoo wa ba ijoba ipinle fun iranlowo lona lati gba eni
to ba kun oju osuwon.
No comments:
Post a Comment