Olu Itori ki Dapo Abiodun ku oriire fun pe o jawe olubori nileejo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 14 September 2019

Olu Itori ki Dapo Abiodun ku oriire fun pe o jawe olubori nileejo

Olu tiluu Itori, Oba Fatai Akorede Akamo, ti ranse ikinni ku oriire si Gomina ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun, fun bo se jawe olubori nibi idajo to waye lojo Abameta, Satide, ose yii.

Gege bi atejade ti Oba alaye naa fi ranse, loju ese ti Adajo igbimo to n gbejo lori ibo gomina to waye ninu osu keta, gbe idajo e kale  nibi to ti da ejo ti Onarebu Abdulkabir Akinlade latinu egbe oselu APM pe Dapo Abiodun nu, lo ti ranse ikinni ku oriire naa, to si tun baa yo pelu.

O ni igbagbo pelu kadara ti so pe Dapo Abiodun naa yoo di gomina nipinle Ogun, O ni inu oun dun pelu iwuri pe okunrin naa saseyori nibi igbejo naa, bo tile je pe awon eeyan eeyan ipinle naa ti koko siyemeji pe boya o le jawe olubori ninu ibo gomina ti won di koja lo sugbon ti Olorun fajulo han awon eda.

Olu Itori wa gbadura pe ki Olorun to yan- an gege bi gomina ko te siwaju lati maa dari e nipa isakoso ipinle Ogun, ati pe igbega Ogun, ajose gbogbo wa ni

No comments:

Post a Comment

Pages