Ibanuje de ba Akinlade nitori bi Adajo se da ejo to pe Dapo Abiodun nu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 14 September 2019

Ibanuje de ba Akinlade nitori bi Adajo se da ejo to pe Dapo Abiodun nu



 Ko digba ti won ba to so ki won to mo pe inu ibanuje nla ni Onarebu Abdulkabir Akinlade to je oludije fun ipo gomina labe egbe oselu APM atawon eeyan e wa bayii nitori bi awon igbimo to n gbejo lori ibo gomina to waye ninu osu keta se da ejo to pe Gomina Dapo Abiodun nu, ti won ni ejo naa ko lese nile, won kan wa fakoko sofo ni.

Nibi idajo naa to waye nileejo majisireeti, to wa ni Isabo, niluu Abeiokuta lawon omo eyin APM ti won wa nibe ti yo ese ni kookan, ko to di pe awon igbimo naa pari idajo won, bo tile je pe won ko tie  po tele.

Awon igbimo eleni meta to gbe idajo naa kale eyi to gba won ni wakati marun un o le die ni won fenu ko lori ejo ti Akinlade pe naa gege bi eyi ti ko ni eri to jinle to.

Adajo Yusuf Halilu to saaju igbimo to n gbejo naa, nigba to n ka idajo e so pe Akinlade to pejo naa ti ko ayanmo lati fidi remi, o tun so pe ki i se lati fidi remi nikan bi ko se pe o tun gba ijakule lori ejo to pe Dapo Abiodun ro dije labe egbe oselu APC.

O so pe awon eleri mokandinlogoji ti akinlade ko kale ko ni eri gidi lori ibo bii egberun meta ati igba le mewaa awon ibi ti ibo ti waye ati pe gbogbo nnkan tawon eeyan naa so ni pe awon lawon fowosi abajade ibo naa laifi tipa mu.

Ati pe ejo won ni won pe ti ko soju eeyan soro gbagbo nile ejo, o wa pari oro e pe ejo naa ko lese nile, o si fagile e ati pelu pe Abajede esi ibo ti ajo INEC kede lese nile, Dapo Abiodun lo wole fun ipo gomina ipinle Ogun.

Bo si se pari idajo naa ni idunnu subu layo awon omo egbe oselu APC ti won ti wa nita. Ti won je ki won tete wole

No comments:

Post a Comment

Pages