Egbe oselu All Progressives Congress
(APC), eka tipinle Ogun ti gboriyin fun idajo ti igbimo to n gbejo lori ibo
gomina to waye ninu osu keta ka nibi ti won ti da Omooba Dapo Abiodun lare gege
bi eni to jawe olubori nibi ibo naa.
Ninu atejade ti Ogbeni Tunde
Oladunjoye, to je akowe olupolongo fegbe oselu naa fi sita leyin ti idajo waye ni won ti gboriyin fawon adajo naa fun ise
takuntakun ti won se lati igba ti igbejo naa ti bere. Eyi ti won lo mu idajo
ododo jade.
O ni ise nla tawon igbimo to gbejo
naa se lo je kawon mo pe Abdulkabir Akinlade tinu egbe oselu APM atawon ti won
sonigbowo e je olukuna patapata nitori bawon ejo won ko se lese nile.
Oladunjoye tun so pe “ O je oun iwuri pe lati gboriyin
fun idajo naa nitori bo se n loo lowo ni won gbe jade lori teifisabn, ti redio
naa gbe jade bee lori ero ayelujara. Eyi to so pe o tu asiri ijakule awon to
pejo faraye ri. Ohun itiju nla lo je pe oludije ati egbe oselu ti won fee fi
tipa sejoba ko nimo eko bo se to nipinle Ogun”.
Egbe oselu APC naa wa so pe amoran
awon fawon eeyan naa ni pe ki won gbagbe gbogbo ikunsinu ki won si pawopo sise
po pelu Dapo Abiodun lori erongba lati
gbe ipinle yii goke. Eyi ti won lo ti n mu ileri e se.
Won wa lo anfaani naa lati dupe lowo
gbogbo awon omo egbe oselu APC ipinle naa fun aduroti won latigba ti won ti
bere ti ko si fi ti eleyameya se bee naa ni won tun gboriyin fawon oniroyin
naa.
No comments:
Post a Comment