Olori
egbe oselu lebo lapapo ti jawe gbele e fun igba die naa fun alaga egbe naa nipinle
Ogun, Ogbeni Abayomi Olufemi Arabambi ti won si ti ni ki Babatunde Atanda
Coker, si je adele e na.
Nibi ipade
oniroyin ti won se Lojobo,Tosidee, ni igbakeji alaga fun ekun ile Yoruba, Bode
Simeon, ti soro yii.
O so pe
awon gbe igbese naa nitori bi Arabambi se kuna lati fopin si wahala to wa ninu
egbe naa nipinle Ogun titi di akoko ti won pe ipade oniroyin naa.
Bode
Simeon salaye pe o se pataki lati bawon oniroyin soro nitori igbese tawon gbe
naa, nitori kawon omo egbe atawon araalu le mo bi nnkan se n loo si ninu egbe
oselu naa.
O tun
fikun oro e pe oun ti gbase lati odo alaga egbe naa Abdulkadri Abdulsalam, ko
to di pe awon gbe igbese naa ati lati je kawon eeyan mo pe okan soso ni egbe
oselu lebo, ko si iyapa ninu egbe naa mo.
Bode
Simeon ni " Lati akoko yii lo, a ti da Abayomi Olufemi Arabambi, duro
gege bi alaga egbe oselu lebo nipinle
Ogun. Niwongba to ti je pe aye ipo naa ko le wa ni ofo, idi niyii taa fi yan igbakeji
e. to tun je alaga egbe naa fun ekun aarin gbungbun Ogun, Babatunde Ranti
Amanda Coker, lati je adele alaga titi digba iyanju yoo fi de "
Simeon tun so fawon oniroyin pe alaafia joba
ninu egbe oselu naa ati pe won ti setan lati sise po pelu egbe oselu mii in fun
ilosiwaju ipinle Ogun.
Bakan
naa ni alaga egbe naa lapapo atawon oloye egbe oselu lebo nipinle Ogun ti so pe
awon ko lowo si gbogbo igbese ti alaga won ti won daa duro naa, Abayomi
Arabambi ti n gbe lori oro ibo gomina to waye.
No comments:
Post a Comment