Ile ejo fagile ejo ti PDP pe Seneto Tolu Odebiyi fun ekun Ogun West. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 9 September 2019

Ile ejo fagile ejo ti PDP pe Seneto Tolu Odebiyi fun ekun Ogun West.Idunnu lo subu layo fawon omo egbe oselu APC ti ekun Yewa iyen Ogun West loni in, nigba ti igbimo ti won n gbo ejo lori ibo to waye fun ti ile igbimo asofin, Abuja fagile ejo ti egbe oselu PDP pe Tolu Odebiyi lori ibo to waye naa.

Nibi idajo naa to waye niluu Abeokuta ni Adajo Yusuf ti so pe ejo tawon olupejo pe naa ko lese nile ati pe bigba teeyan ba n fi akoko sofo ni.

Idi niyii to fi fagile igbejo naa, to si ni ki Tolu Odebiyi maa se faaji e lo nile igbimo asofin  niluu Abuja gege bi seneto fun ekun Ogun West.

Bi won si se pari idajo lawon alatileyin okunrin oloselu naa fi idunnu won han, pelu akole lorisirisi lowo ti won fi  n dupe lowo Olorun.    

No comments:

Post a Comment

Pages