Igbimo to n gbejo lori ibo asojusofin to waye ti fagile ibo to
gbe Onarebu Kolapo Korede Osunsanya tegbe oselu APC wole gege bi asoju-sofin
fun ekun ti aarin gbungbun Ijebu Central federal constituency, o si ti pase pe
ki atundi ibo waye laarin aadorun ojo.
Taiwo Shote, to dije labe egbe oselu Peoples Democratic Party (PDP) lo gbe okunrin
naa lo sile lati pe oludije APC naa lejo pe ibo to gbe okunrin naa wole ninu
ibo ti won di lojo ketalelogbon, osu keji, odun yii, nibi ti won ti kede
Osunsanya gege bi eni to jawe olubori ko lese nile, o lowo ojooro ninu.
Ninu idajo ti Adajo Wakkil Alkali Gana saaju
fun lo ti fagile awon ibo to waye ni woodu karun, nijoba ibile Ijebu Ode, bee
naa ni won tun fagile ti woodu kewaa, lagbegbe keta ni Odogbolu ati gbogbo eyi to waye woodu kejo ni Ijebu
North-East.
Ile ejo naa wa pase ninu idajo won pe niwongba
ti ibo ti olupejo ati olujejo ko tii to egberun merin ti won fi ju ra won lo,
ti won si ti fagile bi egberun mejo ati irinwo, ko ye ki ajo eleto idibo kede
Osunsanya gege bi eni to wole labe ofin idibo..
Won tun
so pe nnkan to ye ki alajo eto idibo naa se ni pe o ye ki won so pe ibo naa ko
tii kese jari, ki won si seto atundi ibo lawon ibudo toro naa kan.
Idi niyii ti Adajo naa fi so pe ko wole gege
bi asoju sofin, o si fagile ibo pelu ase pe ki atundi ibo waye laarin aadorun
ojo si akoko yii.
Nigba to n soro nipa idajo naa, Shote sapejuwe
idajo naa gege bi aseyori nla fun ofin ile wa. O ni inu oun dun fun idajo to
waye naa, bo tile je pe won ti fi igbejo naa fale latile. O wa dupe lowo Olorun
ati gbogbo eeyan e ni agbegbe Ijebu
Central.
No comments:
Post a Comment