Arabinrin Irene Kokumo, to je akowe
agba nileese to n ri si oro ifeyinti lawon ijoba ibile nipinle Ogun, ti so pe
owo tijoba n na lori awon osise feyinti lawon ijoba ibile, ati ileese to n ti
si eto eko iyen SUBEB losoosu fee to milionu lona egberin naira. Ati pe owo to
si wa nile ti won fee san gege bi ajesile ti won fee san laarin osu kejo odun
2011 si odu kefa 2019 labe ifeyinti won fee to bilionu metalelogbon naira.
Obinrin yii soro yii lakooko to n
gba awon igbimo to n ri si oro ijoba ibile labe ile igbimo asofin ipinle Ogun
lalejo ni ofiisi e. O so pe bo tile je pe isakoso to wa lode ti seleri pe oun
yoo san awon owo tawon isakoso to ti sejoba je sile fun won.
Kokumo tun salaye pe eto isuna ti
won la kale fi aye lati san owo osise feyinti ni egberun mokanla ati egbeta
le merindinlogun awon osise feyinti lati
ipele odun 1991.
Bee lo tun fikun oro e pe akosile
ileese to n ri si oro osise feyinti lawon ijoba ibile fi han daju pe isakoso to
wa lode yii ti n wa ona lati gbe iwe owo awon osise feyinti jade fawon ijoba
ibile lati fawon eeyan naa ni anfaani rowo won ti won ti sise fun lakoko ti won
sin ijoba gba.
Kokumo tun so pe leyin milionu to
din die legberin naira tawon n san losoosu gege bi owo ifeyinti,o ni ileese naa tun ti san bilionu merin ati
milionu mefa naira laarin osu kin in ni si osu kefa odun yii bakan naa.
O ni eyi to je ileese logun ni tawon
osise feyinti to nii se ijoba ibile ati oro eko iyen SUBEB to ni ipele odun
1991. O so pe ijoba ipinle Ogun sise
lori awon ipenija tileese naa n koje nipa sise atunse awon ofiisi to wa nibe,
ki won si se awon ohun elo igbalode sibe.
Ninu oro Onarebu Akeem Balogun, to
je alaga igbimo naa, lo ti gboriyin fun awon to n sakoso ileese naa fun bi won
se sise won tokantokan bee lo wa muu dawon loju pe ki won dide lati wa ona ti
won le gba san awon owo ajesile to ku tawon osise feyinti lawon ijoba ibile ati
toro eko SUBEB
No comments:
Post a Comment