Egbe apapo awon onigbagbo,iyen Christian
Association of Nigeria (CAN) ti ro awon
eeyan latii ma se maa fi igbekele won nipa eto abo le ijoba lowo mo ati awon
alaabo ilu bi ko se owo Olorun.
Oro yii jade nibi apero kan ti egbe
naa se fawon alaabo ilu, eyi to waye lojo Isegun, Tusidee, ni soosi, ile Isura
Olorun, Treasure House Of God to wa ni Agbeloba, niluu Abeokuta.
Ninu oro alaga egbe CAN nipinle Ogun,
Bisoobu Tunde Akinsanya so pe awon ti setan lati sise pelu awon olopaa atawon
alaabo ilu yooku lati gbogun ti iwa odaran lawujo, ki eto abo to peye si le
waye.
O ni gbogbo bo ba n se loo lawon
setan lati maa fawon alaabo ilu lati le maa fi ran won lowo nini ise abo ilu ti
won se. Okunrin naa tun mu dawon alaabo loju pe gbogbo ile ijosin ni won ti
setan fara won sile ki igbogun tiwa odaran naa le di afiseyin teegin fi aso.
Bisoobu naa tun salaye pe arero ojo
naa se pastakli lati le je kmi gbogbo le jo sise po, ki won si fi iriri kun
iriri won lati wa ona abayo si isoro to n dojuko abo nipinle Ogun.
Lara awon alaabo ilu to peju pese
sibi eto naa ni awon alaabo ili, sifu, asoju lati odo awon olopaa, awon
agbofinro, awon So-Safe Corps, awon eso asobode atawon mii in tise won nii se
pelu eto abo nipinle naa.
Ninu iwe apeleko e to ka,eyi to pe
akole e ni ohun to fa ijakule awon asaaju, alaga egbe CAN, Akin-Akinsanya salaye pe ajosepo to danmoran gbodo bere latodo ileese elekejeka to je tijoba
atawon araalu lona ti yoo je ki ilu bo lowo awon alaabo idojuko ta n fojoojumo
koju, o ni abo naa ko gbodo fi da ijoba nikan
.
Gbogbo awon olukopa nibi eto abo naa
ni won gba lati te siwaju lori ona ti orileede yii yo fi ja ajabo lori idojuko
eto abo ta n koju. Pelu pe kawon araalu naa setan lati sise po pelu awon araalu,
ki awujo wa se dun un wo loju, ki won si ta awon alabo ilu lolobo ti won ba
kefin awon oniwa buburu laarin won.
DC Awolowo Ajogun, to je igbakeji
komisanna olopaa nipinle Ogun, ninu oro e to soju komisanna awon olopaa nibi
apero naa so pe okan lara awpon isoro tawon n koju ni bawon eeyan se maa n fa
seyin lati ta won lolobo nipa iwa odaran,o ni ti ko si ye ko ri be, se lo ni
opo won maa n sa lati fi okodoro idi oro won mule.
O wa lo akoko naa lati ro awon
araalu lati ma se beru ti won ba lawon asiri to nii se iwa odaran lowo, o ni
awon setan lati daboobo wonti ko ni si ewu.
No comments:
Post a Comment