Idunnu subu layo olori ile igbimo
asofin nipinle Ogun, Olakunle Taiwo Oluomo, lojo Eti, Furaide, nigbati igbimo
to n ri si ibo asofin to waye ninu osu keta, odun yii, daa lare gege bi eni to
jawe olubori fun ibo omo ile igbimo asofin, ti ekun ifo kin in ni.
Nibi idajo eleni meta ti Onidajo Adenike
Coker, saaju fun ni won ti so pe ejo ti olupejo e latinu egbe oselu APM pe e ko
lese nile, ti won si daa ni bi omi isanwo.
Ninu oro e leyin ti won pari ejo
naa, Olori ile igbimo asofin naa, Tawo Oluomo fi emi imoore e han si Olorun fun
bo se jajabo ninu ejo naa.
Bee lo tun dupe lowo awon onidajo
naa bi won se je kawon eeyan nigbagbo ninu idajo ododo. O wa so pe idajo to waye
naa yoo tubo foun lagbara lati le sise oun gege bo se to ninu eto idajo ipinle
Ogun.
Oluomo tun wa gboriyin fawon eeyan
agbegbe e lati ifo kin in ni to ti wa fun atileyin ti won se foun pelu ileri pe
oun yoo tubo je asaaju rere fun won, laini huwa odale ife ati ooto ti won ni si
oun.
O tun wa lo akoko naa lati ki Gomina
Dapo Abiodun (MFR) tipinle Ogun lori ise takuntakun to n se lati je ki irorun
de ba eto idajo lati le je ki won si se won bo se to ati bo se ye.
O wa ro awon egbe oselu ti won ni
ikunsinu lati gbagbe awon nnkan to ti koja, ki won si je kawon jo sise po fun
eto isakoso ijoba ati asoju rere.
No comments:
Post a Comment