-Okunrin
naa ko le rin mo
Iroyin to te wa lowo bayii ni pe ara
agba osere onitiata nni, to filu Abeokuta sebugbe, Alaaji Yekini Oyedele, topo
awon eeyan mo si Baba Legba ko ya o, adura lawon ebi e n gba fun un.
Gege bi a se gbo, inu ile agboole kan ti
okunrin naa n gbe ni Itoku, niluu Abeokuta, ni Baba naa wa, nibi ti ko ti le
dide lori ibusun e, ti won lawon eeyan e, lo n gbe e dide.
Agboole ti Baba Legba n gbe |
Ohun taa gbo ni pe lati inu osu kejo
lokunrin naa ti wa ni idubule aisan ninu yara to n gbe, ti won si ti na opo owo
sugbon won ni nigba ti ko si owo mo, ni won fi daa pada sile.
Nigba ti oniroyin wa de ile Baba
naa, oun nikan lo wa ninu yara, ti oro e ko loo soke rara, ninu oro to ba wa so ni pe ojoojumo ni ara ni
oun, toun ko si ri onitoju gidi.
O fikun oro e pe owo toun yoo fi se
ayewo ara ti won loun loo wa wa loun ko ri, toun fi pada sinu ile. O wa ro
gbogbo omo Naijiria lati dide ran oun lowo, nitori inira yii ti poju.
No comments:
Post a Comment