Egbe oselu All Progressives Congress
(APC), tipinle Ogun ti kan sara sawon olopaa digboluja tie ka awon to n ji
eeyan gbe atawon egbe okunkun nipinle Ogun lori akitiyan won bi won se gba awon
eeyan marun un sile ninu eyi ti pasito wa ninu won ti won je omo ijo Ridiimu tawon
ajinigbe jig be lale Ojobo, Tosidee, ose to koja.
Ninu atejade ti akowe olupolongo
egbe naa, Tunde Oladunjoye, fi sita lojo
Aiku, Sannde, ni won ti gboriyin fawon eeyan naa eyi ti Bashir Makama,
komisanna awon olopaa nipinle Ogun saaju fun femi igboya ti won lati rii pe won
tete gba awon ti won jig be naa sile lowo awon onise ibi naa.
Bee ni egbe oselu naa tun gboriyin
fun Gominma Dapo Abiodun lori ilakaka e
lati rii pe iwa odaran doun afiseyin nipinle naa ki alaafia si joba laarin awon
olugbe.
Won ni igbese ti Dapo Abiodun gbe lo
je ki Aare Mohammadu Buhari ati oga olopaa patapata lorileede yii naa tete ja
fafa nipa pipese oko ofurufu elikopta, eyi to ran awon olopaa lowo lenu ise won
lati tete gba awon ti won jig be naa sile lagbegbe Ogunmakin ati Ogbere.
Bee ni egbe oselu APC tipinle Ogun
tun wa dupe lowo oga olopaa patapata naa lori ipinnu e lati gbe igbimo ajosepo
lori oro aabo dide nipinle naa.
Won
wa so di mi mo pe eto aabo, ojuse
gbogbo araalu ni, won ni kaka ki won maa ba ijoba se orogun, ohun to se Pataki lakooko
yii ni ki gbogbo won jo fowosowopo lati gbogun tawon odaran lawujo, ki alaafia le
wa niluu.
Bee ni won wa gba awon olopaa atawon
eleto aabo yooku nimoran lati ma se sinmi tabi kaare lori emi ati dukia awon
eeyan.
No comments:
Post a Comment