O soro yii
lakooko to n bawon oniroyin forojomitoro oro ni ofiisi e laaaro yii lori awon
omo ijo Ridiimu marun un tawon ajinigbe ji gbe lona Ijebu si Eko sugbon ti won
ti ri won pada.
Gomina tun fi kun oro e pe onile tabi oni nnkan ini to ba gba
awon odaran sile, wiwo nijoba yoo wo ile naa ti won yoo si ba awon nnkan ini to
ni je.
O tun so di mimo pe laipe nijoba oun yoo se ifilole ajo eleto
abo tawon oloyinbo n pe security trust fund, pelu igbekale ofin siwaju awon omo
ile igbimo asofin lati jiroro lori idajo fawon odaran towo ba te.
Dapo Abiodun tun so pe igbese ti n loo lowo lati gbogun tawon
odaran, idi niyii ti won fi pase pe ki won satunse lawon ona kilomita meedogbon
ona Sagamu/Ore/Benin-ati Eko.
O ni" E je ki n kilo fun gbogbo awon onile ati oni nnkan
ini ti won gba awon odaran sile towo ba te ni yoo wo ile e ti won yoo si ba
awon nnkan ini e je.
" Mo fee so fun yin pe ko sibi kan nipinle Ogun to yo lowo
awon odaran yii nipinle Ogun, A gbodo wa won jade, ki a si mu won jade lati fi
won jofin.".
Dapo Abiodun wa gboriyin fun Aare Muhammadu Buhari fun bo se
pese awon ohun elo lati fi gbogun tawon odaran nipinle Ogun.
Bee lo tun dupe lowo awon olopaa fun ise akoni ti won se lati le
ri awon eeyan marun un naa pada lona Ogbere si Sagamu, lona marose Benin si Lagos.
No comments:
Post a Comment