Awon agbe eleja osin Eriwe, Ijebu- Ode fee iranlowo ijoba ipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 5 August 2019

Awon agbe eleja osin Eriwe, Ijebu- Ode fee iranlowo ijoba ipinle Ogun

  Titi di akoko ti a wa yii, inu ibanuje okan lawon agbe eleja to wa ni abule oko Eriwe ni Ijebu ode  wa bayii lori bi ojo aroroda se se won lose, to si ba nnkan je fun won patapata.

Awon eeyan naa ti rawo ebe si Gomina Dapo Abiodun, ati ijoba apapo lati dide iranlowo sawon lori bi agbara ojo se gbe awon eja towo e to milionu lona irinwo naira lo lawon abule odo eja naa.

Awon egbe agbe eleja  ti won n je Catfish and Allied Farmers Association of Nigeria toro naa kan so pe agbara ojo to ro lojo kokandinlogbon, osu to koja yii, lo sakoba nla fawon, to si gbe opo eja to ti to koore atawon kekeke lo.

Nigba  to n soro nipa isele naa, Ogbeni Sunday Sunday Talabi ati Pasito Oluniyi Olukoga to gbenuso fun won salaye pe ibanuje okan nisele to waye naa je fawon, nitori opo won lo ti fee ran ni oko gbese.

Gege bi won se wi, won ni agbara ojo naa ki i se nnkan tuntun loju awon agbe abule naa sugbon awon toro naa kan ju lawon to ko ile fun eja osin won.

Won ni ti iru nnkan bee ba sele tele igbese yawon maa n gbe ni lati so fawon alase  to ni oko naa, amo se ni won so pe won kan maa n way a foto nnkan to sele, ti won yoo si ki won pele laise iranlowo fun won.
Won ni isele to sele yii ni ko tii waye ri lati nnkan bi ogun odun ti won ni abule naa, to si je iyalenu fun won.

 Ninu oro ti Pasito Sunday Isoma, to je alaga fegbe awon agbe eleja osin tipinle Ogun iyen  Catfish and Allied Farmers Association of Nigeria, lo ti so pe  opo awon ibi ti ijanba naa sele si labule ni lo gbe nnkan won lo nigba topo okoowo awon agbe naa tun baa lo pelu.

A tie gbo pe okan lara awon agbe eleja osin naa tokan e ti bale pe oun yoo ta eja lojo keji tisele naa waye, to si tip e awon onibara e lati wa baa ra, lo bu sigbe nigba to de odo eja e, ti ko ba nnkankan mo, gbogbo e ni agbara ojo naa ti gbe e lo.

Bi omode ni Fatai Abiodun, Alebiosu Sins ati Adebayo Seun se n sunkun lakooko ti won n ba oniroyin wa soro nipa ijanba ti ojo naa mu bawon
.

Alebiosu so pe milionu mejo naira ni eja toun padanu bee naa ni
Sina Adebayo so ni tie pe eja egberun mejila loun padanu, gbogbo won ni won si n pariwo gbese nla ni lawon je.

Ni bayii, egbe agbe eleja osin naa ti wa rawo ebe si Gomina Dapo Abiodun atawon eleyinju aanu lati gbawon lowo nnkan to le fa iku ojiji ati gbese nla yii, nitori opo won ni ko si ona abayo mii in fun mo.
No comments:

Post a Comment

Pages