Beeyan ba je ori ahun, ko si ki omi
maa bo loju e to ba de ibi ti won ti seye ikeyin fun Kehinde Akhigbe, osise
alaabo So-Safe Corps tawon adigunjale yinbon fun. Lojo Abameta, Satide, ni won
sin okunrin naa.
Nibi eto isinku naa to waye ni ile isinku
Lantoro, to wa lona Kobape niluu
Abeokuta lawon molebi atawon eeyan okunrin naa to fi mo awon osise alaabo egbe
e ti fekun ranse si ekun, pelu awon orin aro lorisirisii.
Bee lawon osise So- Safe naa seye
ikeyin fun akoni won to loo naa, awon gan an naa ni won gbe oku ti won si sin
in leyin ti won ti se isin ikeyin fun un.
Ninu osu kefa odun yii lawon
adigunjale yinbon fun okunrin naa ni adugbo Community to wa ni Oke Lantoro,
Abeokuta lakooko ti ajo So-Safe koju ija sawon adigunjale naa.
Loju ese ni won si ti gbe okunrin
naa loo si osibitu FMC niluu Abeokuta, nibi to ti lo ose meloo kan ko to di pe won tun gbe loo si osibitu LUTH niluu Eko.
A gbo pe ojo to pada dele lokunrin akoni naa dagbere faye iyen lojo Abameta, Satide, ojo ketadinlogbon osu to koja yii. Odun mejidinlaadota ni Mathew lo laye.
A gbo pe ojo to pada dele lokunrin akoni naa dagbere faye iyen lojo Abameta, Satide, ojo ketadinlogbon osu to koja yii. Odun mejidinlaadota ni Mathew lo laye.
Soji Gazallo, to je oga agba fun ajo alaabo naa lo saaju awon
eeyan e lo sibi ayeye isinku naa, eni to ba si ri okunrin kaa yoo ti mo pe
ajalu nla loro iku okan lara awon omoose e naa.
No comments:
Post a Comment