Inu ibanuje lawon alaabo fijilante
tile Naijiria VGN ti eka ipinle Ogun wa bayii lori bi won se padanu okan lara
won, Aderibigbe Idowu lakooko ti won fee gba awon omo ijo Ridiimu marun un
tawon ajinigbe ji gbe sile.
Gege bi atejade ti oga agba fajo
fijilante nipinle Ogun, Ogbeni Nureni Adedoyin fi sita lo ti so pe lojo
Abameta, Satide, ojo keta, osu yii ni lokunrin naa padanu emi e lagbegbe J3,
Ogbere, nijoba ibile Ijebu East.
Won ni okunrin naa wa lara awon to
fee gba awon eeyan naa la, lakooko tawon ajinigbe naa fija peeta pelu awpn
apapo alaabo ilu ni won so pe ibon ti ba a ninu igbo ti won ti n wa awon eeyan
naa.
Adedoyin salaye pe iku osise awon
yii dun awon pupo nitori okan ninu awon akoni won ti ko fise e sere ni. encies
No comments:
Post a Comment