Ese o gbero lopin ose to koja, ni
gbongan M2 Arena Event Centre, niluu Eko, nibi ayeye igbeyawo Kanyisola
Fagbayi, amugbalegbe igbakeji gomina nipinle Ogun, Omino-ero Noimot Salako-
Oyedele ati iyawo alarede e, Arabinrin Oladoye Odunsi.
Igbeyawo naa la gbo pe iyawo gomina nipinle
Ogun,
Arabinrin Bamidele Abiodun,Igbakeji gomina
funra e ati oko e Alaaji Bode Oyedele naa ko ti gbeyin ni won ti wa bu ola fun
oko ati iyawo lojo naa.
Nigba to n gba toko tiyawo nimoran
lojo naa, Oloye Ademola Akinle Shabi to
je alaga pataki nibi ayeye gba awon onigbeyawo ojo naa nimoran lati jo maa gbe
ni irepo, ki won si maa fi adura ran ara won lowo loro ohun gbogbo ti won ba n
se.
Bee lokunrin naa tun gbawon nimoran
lati ma se gbagbe awon obi won pelupelu ipo ti won di mu lawujo, o ni okan lara
asiri adun igbeyawo ni, o wa fi adura ran awon mejeji lowo pe Olorun yoo ba won
gbe idile won ro.
Iyawo Gomina ipinle Ogun lo dari
gige akara oyinbo igbeyawo naa, lara awon to tun wa nibe ni Iyawo olori awon
osise gomina nipinle Ogun, Alaaji Shuaib Salisu, Onarebu. Jimoh Ojugbele, to n
soju sofin fun ekun Ado Odo Ota niluu Abuja, Arabinrin Modele Sarafa- Yusuf,
oluranlowo gomina pataki lori eto iroyin ati Lanre Bisiriyu, olori awon osise
nipinle Ogun, to saaju awon akowe ijoba
atawon oloye egbe oselu APC.
No comments:
Post a Comment