Ijoba ipinle Ogun ti ranse
ibanikedun si Seneto Buruji Kashamu, asofin tele to n soju ekun Ijebu nile
igbimo asofin niluu Abuja fun ti Mama e, Wulemotu Kashamu, to jade Lojoruu, Wesidee, ana niluu Eko.
Gege bi atejade ti Ogbeni Kunle
Somorin, akowe Gomina nipa nipa eto iroyin fi sita loruko Gomina Dapa Abiodun
lo ti so pe Mama naa gbe igbe aye emi gungun pelu bo se lo odun merindinlogorun,
lorile alaaye.
O ni pelu bi Mama naa se dagba to,
ko seni to fee ki eeyan e fi sile lo nitori naa awon mo pe ipo edun okan ni
Buruji Kashamu yoo wa idi niyii tawon fi kii ku aseyinde mama e naa.
Gomina Dapo Abiodun sapejuwe Mama
Kashamu gege ni eeyen jeje, to ni anfaani lati ni iru eeyan pataki bi Seneto
Buruji atawon mii in ti won tinu e jade gege bi alaseyori omo.
O tun so pe Mama
Wulemotu to doloogbe naa tun ni opo nla to wa bi asiri nla fawon omo e bi won
se gberi gege bi onisowo nla, to si mo nipa itoju awon omo.
Gomina tun fikun oro e pe gege bi
onigbagbo, oun mo pe irinako eda yoo dopin lojo kan, bo ti wu keeyan pe to nile
aye. O ni oun mo pe mama naa ki i se
musulumi afenuje, olusin gidi lo pe won, to ni o si fesin le awon e lowo.
O wa gbadura pe ki Olorun tu Seneto Buruji Kashamu atawon ebi naa ninu, ki o si wa
pelu won O wa ni loruko ebi oun ati awon omo ipinle Ogun ni won ba Kashamu daro
iya e naa.
No comments:
Post a Comment