Ileese alaabo So- Safe Corps lawon
ti gbaradi lati sise po pelu awon alaabo yooku lati pese eto abo to peye fawon
araalu fun ti odun ileya ati leyin e.
Soji Gazallo, Oga agba fun ileese
naa lo soro yii lakooko to n baa won oniroyin sori lori imurasile fun odun
ileya to n bo lona.
Bee lo tun lo akoko naa lati bawon
osise abe e soro lati rii pe won ko fawon odaran laye lati da ilu ru.
Soji Gazzallo ti wa
pase pe ki won pin awon osise alaabo So- Safe Corps kaakiri gbogbo awon ibi to
ye fun odun to n bo lona naa.
O ni pataki fun won ni
lati ri pe awon araalu fayo ati idunnu sodun naa. Bee naa ni agbenuso fajo naa,
Moruf Yusuf tun ro awon araalu lati je eto abo mu lokan
won lokunkun dun pelu idaniloju pe ise ajosepo abo pelu gbogbo alaabo yooku yoo
mu eso rere jade.
O wa fi awon nomba
foonu kan sita fun enikeni to ba ni ipenija tabi gbo nipa awon odaran lati pea
won nomba naa. Awon nomba naa niyi 09069392064 ati 08035479930
No comments:
Post a Comment