Ka ni awon omo eyin Gomina Dapo Abiodun ba mo pe irun yidi odun ileya to waye ni loni-in, Sannde, ojo Aiku, yoo di nnkan ti gomina tele nipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun, yoo gba iyi mo won lowo ni, o seese ki won ti kowo oselu boo debi pe won ko ni je ki okunrin naa wa kirun nibi ti won wa lojo naa.
Sugbon won
ko mo rara, bi ala gan an lo se ri nigba ti won ri okunrin to n soju ekun Ogun
Central nile igbimo asofin, niluu Abuja to yo si won pelu awon emewa e.
Sebi ko to di
pe Amosun debe lojo naa, ni gbogbo yidi naa paroro topo awon musulumi to wa
kirun loo sibi ti won ti fee kirun, awon eeyan ko tie mo pe awon asoju Gomina
Dapo Abiodun tie wa nibe, gulogulo ni gbogbo won loo jokoo saye ti won pese fun
won.
Nigba to di
nnkan bii aago mewaa ni Seneto Ibikunle Amosun, ati minisita ti won sese daruko
lati ipinle Ogun, iyen Alaaji Lekan
Adegbite atawon emewa gomina yo, ti ariwo si so fun bii iseju lawon eeyan fi
ariwo ki won kaabo loo sori ibi ti won ti fee kirun.
Eni to ba ri
Alaaji Shuaib Salisu to je olori awon osise gomina, to soju Gomina Dapo Abiodun
atawon eeyan yooku e yoo ti mo pe lojiji ni Amosun atawon eeyan e yii bawon.
Bo tile je
pe won muu moram won fi se iso inu eku, sugbon awon to ri won bi won se n ki
awon eeyan naa kaabo, ti won n di mo won yoo ti mo pe ko denu won rara.
Bi igba
tawon ero yidi ri olugbala won loro ri, nitori nigba naa ni won to turaka.
Koda, inu Alaaji Sugar to n ki awon
eeyan kaabo dun, to si n ki Amosun ni mesan mewaa pe omo Ajiri.
Leyin to de
ni Imaamu agba, Alaaji Orunsolu to de yidi, iyen aago mewaa ti koja, ni won to
bere irun lojo naa. Gbogbo ero okan awon ara yidi ni pe boya Amosun yoo bawon
soro gege bi i se e nigba to wa ni gomina, rara o, ko se bee rara, bo se kirun
tan, loun atawon eeyan kuro ni yidi.
Bo si se n
loo lawon eeyan naa ti n lo, oro ti asoju gomina, Alaaji Shuaib Salisu so loruko gomina, won ko guro gbp, ariwo Amosun
lawon eeyan sa n pa, a fi bi eni pe oun lo si wa nijoba nipinle Ogun,
Se la gbo pe
inu awon omo eyin Dapo Abiodun to wa nibe ko dun si nnkan to sele naa.
No comments:
Post a Comment