Ipese ise ti Gomina Dapo Abiodun,
tipinle Ogun seleri fawon eeyan ipinle e la gbo ifilole e yoo waye Lojobo,
Tosidee, ose yii ni gbongan asa ibile, Cultural Cente , Kuto, niluu Abeokuta,
bere ni deede aago mejila osan.
Gege bi atejade ti Ogbeni Kunle
Somorin, akowe iroyin fun Gomina Dapo Abiodun. fi sita lo ti salaye pe nibi
ifilole naa lo ti ni aye yoo ti wa fawon odo to ba n wase atawon to ti nise lati
foruko sile lori ero ayelujara fun iwase naa.
Bakan naa ni won tun ni eto naa tun
wa fawon to ba fee kose lati ko won atawon ti won ti jade nileewe giga ti won
ko ti nise ti won niwe eri won lowo.
Akowe iroyin fun Gomina tun fikun
oro e pe eto iwase ti gomina sagbekale e ni nnkan bi osu kan seyin, laarin
wakati meji ti won fi koko se, awon bii egberun marun un lo ti foruko sile, ko
to di pe kinni naa denukole nigba naa.
O so pe ijoba ipinle Ogun ti sise po
pelu aladaani lati pese ise fawon odo okunrin ati obinrin ti Olorun fun ni ebun
lati lo ebun won.
Kunle Somorin tun so pe " Gbogbo awon to
kawe jade nileewe yunifasiti atawon to kose owo nipinle yii la o sagbara wa
lati pese ise fun won. Ki i se nipase ise ijoba nikan la fi fee fun won
Ko ma baa dabi eni pe a kan fakooko
awon eeyan naa a yoo gbe abadofin kan to nii se pelu oro ise loo sile igbimo
asofin, eyi ti yoo fun awon olokowo ti won fee da ise sile nipinle Ogun lati
rii pe won koko mu awon odo ti won foruko sile naa ti won ba bere ise won nibi.”.
O tun so pe Gomina Dapo Abiodun, ti
yan Ogbeni Lekan Olude, to nileese Jobberman
sile gege bi oludamoran pataki lori ipese ise ati riro odo lagbara lati sakoso eto
naa.
Bee la tun gbo pe nibi ifilole ti
yoo waye lojo Tosidee yii ni Gomina Dapo Abiodun ti n sise po pelu banki ile wa
iyen CBN ati banki agbaye lati satileyin fun egberun lona ogoji agbe fun
idokowo ise agbe, lati fofin pin si osi ati iponju lawujo.
O ni egberun mewa odo ni Gomina Abiodun
fee satileyin fun ipse ege, agbado ati iresi, eyi ti ipinle Ogun ti goke ipese
e latile wa.
A gbo pe agbe kookan ni won yoo fun
nile pelu awon nnkan ogbin laeon oko won.
No comments:
Post a Comment