Ese o
gbero lojo Abameta, Satide, to koja yii, niluu Abeokuta nigba ti Onimo-ero
Jonathan Olubunmi Onajobi, to je akowe agba nile igbimo asofin nipinle Ogun
segbeyawo alarinrin fomo e Tomilola.
Igbeyawo
naa lo waye laarin Tomilola ati oko e, Augustine. Isin idapo mimo yii lo waye
nile ijosin Kerubu ati Serafu, Ebenezer Communion, Araromi, Asero, niluu
Abeokuta.
Nibi tawon
eeyan pataki ti peju pese, lara won ni Onimo-ero Bisirimiyu to je olori awon
osise nipinle Ogun atawon akowe ijoba nipinle Ogun.
Alagba
Taye Olagoke, igbakeji Baba Alakoso lo idapo toko tiyawo naa nigba ti Alagba
Olabinke se iwasu lojo naa, nibi to ti gba awon onigbeyawo ojo naa nimoran lati
maa gbe igbe aye alaafia.
Bee lo tun foro inu Bibeli Peteru kin in ni
ori keta ese kinni de kefa gbawon niyanju, bee lo tun gba iyawo nimoran lati
maa bowo fun oko e.
Egbe
akorin ijo naa lo forin emi dawon eeyan naa lola. Leyin iwasu ni won fowo si
iwe eri igbeyawo ti won si fun toko tiyawo nigba ti won ti foruka si won lowo.
Gbongan
DLK to wa ni Lemme, ni ayeye igbalejo ti waye, nibi ti tokotiyawo naa ti ge
akara oyinbo, tawon eeyan si bawon sajoyo.
Ko to to
akoko naa, Lojobo, Tosidee, ose to koja ni ayeye mon mi n mo o ti koko waye
nile Baba Iyawo, Onimo ero, Jonathan Onajobi.
No comments:
Post a Comment