Beeyan
ba gesin ninu awon odo ogun ti won sese gbase lowo ijoba ipinle Ogun, Lojobo,
Tosidee, ana, ko nii kose nitori binu won se dun too fun oore ti Olorun se fun won
lairotele.
Nibi
ifilole ipese ise fawon odo atawon ti ko nise lowo tijoba ipinle Ogun se lawon
eeyan naa ti soriire, ti won si n ba eleda won sajoyo.
Latigba
ti Gomina Dapo Abiodun ti gbakoso ijoba lo ti seleri pe oun yoo pese ise fawon
odo, ti eto naa bere ni nnkan bi osu kan seyin.
Sugbon
nnkan naa ko fi bee loo eyi ti won pe ni omo ogun ise ya lori ero ayelujara, o
dabi eni pe ojo kan ti won ti kede pe o ti bere naa lo ti lo tawon toro kan ko
lanfaani lati foruko sile.
Ojobo,
Tosidee, ana, ni ifilole iforuko sile naa waye nibi ti Gomina Dapo Abiodun ti
si oju abe, ohun to tun je ki eto naa fi larinrin ni ti igbakeji aare orileede
yii, Yemi Osinbajo toun naa wa nibe.
Ise ya ko ni won pe kinni ohun mo lori ero ayelujara jobs.ogunstate.org.ng,
loruko to n je, ti ifilole e si waye ni gongan June 12 Cultural Centre, niluu Abeokuta.
Ninu
oro Gomina nibi ayeye naa lo ti sapejuwe eto naa gege bi aseyori nla fun eto
isakoso e fun erongba lati jo tun ojo iwaju se.
O
so pe iforuko sile awon to n wase naa lori ero ayelujara je eyi ti yoo maa te
siwaju lati pese ise fawon odo to niwe eri ti won ko nise, ti yoo tun pese
idanilekoo fawon to nise owo lowo.
Gomina
loun sakeyesi opo awon odo lo n fese gbale kaakiri lorileede yii nitori ainise
lowo sugbon o da oun loju pe opo adinku yoo wa nipase iforukosile eto tuntun
naa.
Ninu
oro ti igbakeji aare lorileede yii, Yemi Osinbajo, lo ti gbosuba fun ijoba
ipinle Ogun lori eto tuntun naa pelu ileri pe ijoba apapo yoo se iranwo fun
ipese ise fawon odo naa.
O
wa ro awon odo lati lo anfaani ise naa fun idagbasoke eto ogbin, o ni owo ti wa
nile latipase banki to n ri si ileese ati okoowo.
Igbakeji
aare wa ro awon ipinle yooku lati fi ti ipinle Ogun se awokose fun ipese ise
fawon odo.
No comments:
Post a Comment