Se lawon omo ilu Itori ni tile-toko pejo fun ti ayeye odun Ode-Oba olodoodun ti won maa n se, eleekerin iru e to waye loni- in, ojo Aiku, Sannde.
Ayeye naa to
waye ni oja Itori lawon eeyan to fi mo awon oba alade ti wa ba won sayeye naa,
nibi ti won ti fi idunnu won han si Olorun pe o tun so won di odun yii.
Ninu oro ti Oba
Fatai Akorede Akamo, Olu Itori tiluu Itori to tun je olugbalejo pataki nibi
ayeye naa so, o so pe ojo naa ni inu oun dun julo ninu aye yii.
Idi ni pe
latigba ti won ti maa n se ayeye niluu naa, Ode- Oba yii lo so pe o je igba
akoko ti oun ko na kobo, to je pe awon odo ni won ko ara won jo, ti won dawo
fun ti odun naa.
O so pe odun
Ode-Oba naa wa fun lati fi ife so gbogbo awon omo ilu naa po ati pe latigba
tawon si ti bere ni idagbasoke tubo ti n ba ilu Itori.
O wa fi awon
omo ilu atawon ti won gbe ilu naa pe ki won fokanbale pe ileese Dangote yoo tun
pada siluu naa,ki won ma so ireti nu.
O ni oun yoo
tubo tesiwaju gege bi asaaju ilu naa lati ri pe gbogbo awon nnkan amayederun to
ba to siluu naa loun yoo mu wa.
Bee ni Olu-
Itori tun fi kun oro e pe ki awon eeyan e wa ni isokan ati alafia, ki won si ma
se gba janduku laye laarin won. Orisirisi eto alarinrin lo waye lojo naa nigba
ti olorin elesin islam nni, Alaaji Abdulkabir Alayande, topo mo si Ere Asalatu
fere da awon eeyan lara ya.
Lara awon
oba alade to wa nibe ni Oba Kolawole Sowemimo, Olu Owode tilu Owode, Oba Solaja,Olu obada
ti Obada oko, Oniro tiluu Iro atawon yooku bee lawon eeyan jakanjakan naa ko
gbeyin.
No comments:
Post a Comment