Bi nnkan se n loo yii, o seese ki
ija odun meedogun to ti wa laarin awon eeyan agbegbe Ayetoro ati Itele nijoba
ibile Ado-odo/Ota nipinle Ogun pari, ko
si di ohun afiseyin.
Idi ni pe Oloye Olusegun Obasanjo,
Aare orileede yii tele, lo ti seleri pe oun yoo wa opin si nnkan to n da wahala
sile laarin awon mejeeji, ti ija yoo si pari patapata.
Lojo Eti, Furaidee, ose to koja ni
Obasanjo se ipade po pelu awon igun mejeeji ti oro naa kan, eyi to waye ni lusegun
Obasanjo Presidential Library (OOPL) Abeokuta, nibe lo ti so fun won pe akoko
ti to bayii lati pari ija naa.
Wahala to ti n waye laarin awon
eeyan agbegbe meji naa lati odun 2004 la gbo pe o ti mu emi opo eeyan lo topo
ohun ini si tun baa rin pelu.
Nibi to ka Obasanjo lara de, o so
ninu ipade naa pe bi ogun abele ile wa se lagbara to, ti won doju ibon ko ara
won sibe naa awon jokoo papo lati yanju e ni.
O ni ara ere ariyanjiyan ni ija
sugbon o di dandan kawon pe ara won njo lati gbe igbese bi alaafia ilosiwaju
yoo se deba awon iran to n bo.
O ni oun mo pe Akanle yoo seto
igbese alaafia naa nitori aigbele mi, gbogbo nnkan to ba so , o ni oun loun so
nitoti omo ale lo n ri inu ti ki i bi, omo ale ni won n be, kti ki i si gbebe.o
tun wa be won leekan si lati je ki ogun naa pari laarin won.
Oba ilu Ayetoro, to je Onibudo tiluu
Ayetoro-budo, Oba Adewunmi Adeniji Odutala, ninu oro e lo ti mu da Obasanjo
loju pe alaafia ati ilosowaju yoo pada siluu mejeeji.
O dupe lowo Oloye Obasanjo ati
Akanle fun ipa ti won sa lati pe awon mejeeji toro naa papo pelu gbogbo igbese
to ti waye tipe sugbon ti ko so eso rere.
Nigba to n soro loruko awon ara agbegbe Itele, Alh. Kazeem
Ajiboye topo mo si Oluomo naa mu dawon
loju nibe pe ogun ti pari laarin won. Oun naa dupe lowo awon agba mejeeji fun
ife ti won ni lati yanju aawo naa pelu ileri pe gbogbo nnkan to ti sele tele ni
yoo di oun gbagbe.
Abraham Idowu Akanle, toun
pelu olori awon osise aare tele Diakoni Victor Durodola, jo wa ninu ipade ki Obasanjo to debi ipade naa ti
koko gba awon agbegbe mejeeji naa niyanju lati je ki ife ati alaafia joba
laarin won.
No comments:
Post a Comment