Lojo Eti, Furaidee, ose yii, tii se
ojo ketalelogun, ni egbe kan to n se iranti awon alawo dudu to ku sodo lakooko
owo eru iyen African Diaspora Ancestral Clommemoration Institute, ADACI, yoo fi
Oba Fatai Akorede Akamo, Olu of Itori tiluu Itori je Baba isale won.
Gege bi atejade ti Arabinrin Laide
Gold, to je alakoso egbe naa lorileede yii fi sita afin Oba naa niluu Itori ni
ayeye naa yoo ti waye bere ni deede aago mewaa aaro.
Nigba to n so nipa ADACI, obinrin to
je alakoso egbe naa so pe orileede ni won ti daa sile sugbon ti eka e wa ni Naijiria.
O ni idasile e wa fun alawo dudu lati maa fi se iranti ti won ba odo
Mediterranean lo lakooko isowo oko eru.
O fi kun oro e pe Oloye Fakunle Oyesanya ni
aare egbe naa lorileede yii sugbon awon si n wa ile ti won fee fi ko oluu-le-egbe
naa si.
O tun salaye pe ojo kejo, osu kefa,
odoodun ni orileede Amerika ya soto lati maa fi se iranti awon alawo dudu naa.
Laide Gold tun salaye pe idi tawon
fi mi Oba Fatai Akamo gege bi Baba Isale awon ni pe o je Baba to nifee si asa
ati ise, to si feran lati maa ko awon eeyan jo.
Won lawon mo pe Oba naa ki i foju
kere awon to ba sabewo si ofiisi e, to si tun je eni to maa n gbo agboye ati pe
iru e sowon laarin awon oba alaye.
Idi niyii ti won tawon fee fi je
Baba Isale lojo naa, gbogbo eto lo si ti to fun ojo naa lati wa gba adura ati
ire lenu oba naa
Oba Fatai Akamo si ti fi won
lokanbale pe oun ti gba lati je Baba Isale egbe ADACI.
No comments:
Post a Comment