Okan lara awon omo Yoruba Atata ti
ko se e fowo ro seyin ni Ambasedo Dare Olateju Adesope, odu ni kii saimo foloko
ninu awon to n ja fun ilosiwaju ati idagbasoke ile Yoruba, oun ni Aare egbe OPC
REFORMED.
Oni ni okunrin naa sajoyo ojoobi e, nibi tawon
elomin in ti fajoyo e sariya, ti won yoo maa nawo bi eleda, Oga OPC naa ko se
bee, oun to so ni pe ilosiwaju ile Yoruba lo je oun logun, ati pe a ko gbodo
pada si oko eru mo.
O so pe nnkan iwuri ni ki ojoobi eni
soju eni, sugbon ki i se nnkan to bojumu ki eniyan ma dagba sinu agbegbe ati
ayika ti ko wu ni lori rara.
Nitori naa awon tiwon n se akoso ijoba wa
lowolowo lo gba niyanju tori pe ki i se gbogbo eeyan lo ni oore ofe ko maa dake bo ba ri nnkan ti ko to.
O ni ojo tipe tawon ti n pariwo lori
redio atawon iwe iroyin pe ki awon oloselu se ilu daadaa sugbon egbe to ba ti n
yin won nikan ni won feran, egbe to ba ti tako nnkan ti won n se, se ni won maa
ri won gege bi egbe alatako, bee o ni awon o nii dake, ayafi bi won ba
gbo.
Dare tun fikun oro e pe se ni ki
awon ijoba wa mojuto ojo iwaju awon odo, nitori pe awon ni ojo ola orile ede
yii. O ni ominu maa ko oun, boun ba ri awon omokunrin to ye ki won wa lenu ise
ki won maa kopa bi oro aje orileede yii yoo se ni ilosiwaju sugbon to je pe
nidii ipate iwe iroyin(News papers stand) le ti maa ri won ti won maa bere
ariyanjiyan to maa ja si ija lopo igba.
O ni kin ni odo fee maa pariwo
ijangbara fun bi nnkan ba n lo deede? Eni to kan lo mo o nitori pe opo ni ko ri
oinje je beeni ko ni ireti kankan sugbon tawon oloselu wa n gbadun bi eera
suga!
Aare egbe OPC Reformed tun ni orin bamubamu ni mo yo ni won nko, o ni bo ba
doju e, oro Obafemi Awolowo Jeremiah yoo se o.
Nipa oro to n ja rainrain nipa ibudo
fun eran osin awon eya fulani ti won so pe won fee da ruga sile ni ipinle
kookan, o ni se awa ati fulani jo n sowo kan naa ni, bi won ba pa owo nibi ruga
ta ni won maa ko fun? Se ni ki onikaluku se owo re lotooto ki a mo iye ti a fi
pa o.ipinle kookan naa le ni ile osin eran tie,awon odo po niluu ti won ko ri se,
o ni ki won dawon sibe ki won wulo fun ara won ati orile ede.
Ninu awon gomina ipinle ile Yoruba
patapata,gomina ipinle Oyo nikan lo gbojugboya lati so pe oun ko faramo ruga,bi
eyin gomina yooku ba faramo on,e ma gbagbe pe e si maa kuro ni ipo gomina,
beeni Yoruba ki i gbagbe itan. Oba to je to ta ile wa fun eya miran, o ni oruko
re ko nii pare laelae.
O wa kesi awon oba alade, pe ki won ma
wo wa niran o. O ni
oju maa gba oun ti boun ba de oke
okun, o ni awa naa le se ju bee lo sugbon ileri alagbada yii n ko.
No comments:
Post a Comment