Alake tile Egba, to tun je olori oba nile Egba,Oba Adedotun Gbadebo, ti gboriyin fajo alaabo ilu, sifu fawon ise takuntakun, ti won si se baa kegbe laarin awon olopaa atawon alaabo yooku.
Lojo Aje, Monde, ose
yii, ni Oba Gbadebo soro yii lakooko ti oga agba siifu tuntun nipinle Ogun,
Hammed Abodunrin lo ki ni afin e, to wa ni Ake Abeokuta. on Monday.
O ni o da oun loju pe
awon alaabo ilu naa sise won doju amin, ti won ba gbe si ori iwon pelu awon
alaabo yooku lori igbogun ti iwa odaran, jiji epo petiroolu wa, jiji eeyan gba
atawon iwa buburu mii in lawujo.
O fi kun oro e pe awon
alaabo ilu siifu wa si akoko lati safikun eto abo to mehe lorileede yii ati
nipinle Ogun. Oba naa salaye pe awon banki ti bere ise pada nile Ijebu nitori
erongba eto abo tawon siifu atawon alaabo yooku se lati fi le awon odaran to n
yo won lenu.
Bee lo tun so pe
ipinle Ogun lawon eeyan gba pe o je ibi ti abo ti wa daadaa ju lo laarin awon
ipinle Ogun, gege bo se ni akosile eto abo olosoosu se gbe jade.
Alake wa gba oga agba
tuntun fawon sifu lati safikun opolo feto abo to ti wa tele,
Ko to to akoko naa ni
Oga agba fajo sifu nipinle Ogun, Abodunrin ti so pe Naijiria je ilu totobi, o
ni awon tubo safikun agbara lari ri pe awon dabobo emi ati nnkan ini awon eeyan
nipinle naa.
O so pe abewo toun se
wa sodo Alake lati wa ki bee ni oun tun
gboriyin fun un lori bo se n dari awon to wa labe e nipinle Ogun ati Naijiria.
Abodunrin wa mu da
Alake loju pe ajo alaabo ilu sifu ipinle Ogun yoo tesiwaju lati maa sise won,
ti won yoo si ma fowosowopo pelu awon alabo yooku lati ma pese abo lojoojumo.
Awon to tele Abodunrin
sabewo lo sodo Alake tile Egba ni Dyke Ogbonnaya, to je agbenuso fun ileese naa
ati Afolabi Ibrahim.
Lara awon to gba awon
sifu lalejo pelu Alake ni Aare Ganiyu Babayeju, Oba Muftau Akindele, Alakija
Samusideen Ayorinde, Olu-Orile Ikopa, Sarumi M. Ola Yussuf, Agbaakin Rasheed Raji,
Bada-Asojuoba Odekunle ati Aare Baaroyin Layi Labode
No comments:
Post a Comment