Ayederu ipade isokan PDP, ni won se e, ko lese nile –Bayo Dayo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 22 August 2019

Ayederu ipade isokan PDP, ni won se e, ko lese nile –Bayo Dayo


 
Onimo-ero Bayo Dayo, to je alaga fegbe oselu PDP nipinle Ogun, ti so pe kangaru, ayederu ipade lawon kan ti won pe ara won ni PDP se niluu Abeokuta, o ni ko lese nile nitori oun nikan lo lase lati pe iru ipade bee.

Ninu atejade ti okunrin naa fi sita, lo ti salaye pe ipade tawon kan pe akori e ni isokan PDP, eyi ti Ladi Adebutu atawon eeyan se, lo ni won kan fi akoko won sofo lojo naa, nitori oun toun je alaga egbe naa ko mo nnkankan nipa re.

O ni idajo to waye lojo kesan an, osu keje, odun yii, to je eleekeji laarin osu marun un lo ti yanju ohun gbogbo nipa oloye egbe naa nipinle Ogun, nibi toun ti jawe olubori.

Bayo Dayo tun so pe gege bi eni to mofin, to si tun nigbagbo ninu e, awon ti n kan sawon omo egbe ti won ni ikunsinu, awon ti ba awon to da egbe yii sile soro bee lawon si ti n ri esi rere lati odo won.

O ni titi di akoko toun soro yii, ko si iyapa kankan ninu egbe naa, awon oloye egbe toun oun onimo-ero Adebayo Dayo, saaju si ni alase egbe naa nipinle yii.

Alaga egbe naa wa ro gbogbo awon omo egbe lati se suuru, nitori awon alase egbe naa ti n sise labele lati je ki atunse rere pada sinu egbe naa.

Bee lo tun lo akoko naa lati ro awon oloselu Abuja lati fopin si didakun wahala egbe naa nipinle Ogun. O ni o ye ki asaaju maa fipo e sipo asaaju ti won ba yan an si ni. O asaaju to ba fee kawon omo leyin e bowo fun ko ye ko maa wo ara e nile.

O ni se awon ti won fegbe sile lakooko ti ibo asofin fee waye ti won kowo bowe adehun nita gbangba pe egbe oselu Allied Peoples Movement (APM) lawon sise fun ti won si sise tako PDP lo ye ki won maa tele.

O ni titi di akoko yii, won ko tii kowe lati fi bebe fun nnkan ti won se yii, o ni ti won ba fee pada sinu egbe, o lo ye ki won rin in lona tooto.

O wa pari oro e pe gege bi eni to mofin,  ko na egbe oselu PDP nipinpe Ogun ni nnkankan lati fowo ofin mu awon to ba tako ase ileejo lori oro PDP ipinle naa.



No comments:

Post a Comment

Pages