Iya Onarebu Leye Odunjo ti jade laye o - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 2 August 2019

Iya Onarebu Leye Odunjo ti jade laye o
Lana- an, Ojobo, Tosidee, ojo kin in ni, osu kejo,  ni iroyin gba igboro pe Arabinrin Dorcas Odunjo, to je Mama Onarebu Leye Odunjo jade laye.

Gege bi a se gbo, laaaro ana ni won so pe obninrin paju de ti ko le la mo, to si dagbere faye pe o digbose. Odun merindinlogorin ni mama naa lo laye.

Okan lara omo mama naa, to ti figba kan omo egbe ile igbimo asofin leemeji otooto fun ekun Ado- Odo-  Ota kin in ni, Onarebu Leye Odunjo nigba to n ba oniroyin wa soro so pe iya daadaa ni mama naa nigba to wa laye.

O ni iya gbogbo lawon eeyan maa n pe won nitori won ko gbogbo eeyan mora, o ni bi oko ati iyawo naa ba n ja odo mama naa ni won maa n ko won wa lati bawon yanju e.

Leye ni Mama Dorcas Odunjo to je eni to feran awon omode,to si maa n bawon sere, bee lo ni gbogbo awon tawon je omo e lawon feran ore gan-an.

Okunrin to tun dupo seneto labe egbe oselu PDP nibi ibo to koja yii fun ekun Ogun West tun salaye pe tawon ore won ba wa ki won nigba ti won wa ni kekere, laimo eni to bi won, se ni mama oun maa n gbawon towo tese, to maa n toju won bi omo e.

Nipari o ni edun okan lo je foun pe oun ko ni ri mama oun mo laye, nitori wura oun toun fi n yangan lo ti loo yii.
 

No comments:

Post a Comment

Pages