Lati le je ki nnkan rorun fun onise aje, aladaani atawon olokoowo nla, ijoba ipinle Ogun ti n gbe igbese lati bere ise atunse oju ona lawon ona meta to je ti ijoba apapo.
Gege bi atejade ti Ogbeni Kunle
Somorin, to je akowe iroyin fun Gomina Dapo Abiodun fi sita, lo ti so pe Gomina
soro naa lakooko to n se ipade po pelu awon alakoso banki lagbaye, eyi ti
Ogbeni Rachid Benmessaoud saaju, to waye niluu Abuja.
Nibe lo ni o ti so pe oun ti toro
aye lowo ijoba apapo lati tun awon ona naa se.
Awon ona naa ni Ikorodu – Ogijo – Sagamu
, Epe – Ijebu – Ode road ati Eko – Ota – Abeokua. Awon ona naa ni won so pe won
wonu ara won lati ipinle Eko si Ogun ki irorun le bawon onise okoowo ati aladaani.
O ni Gomina Dapo Abiodun gbe igbese
naa nitori pataki ti oro aje n ko lori awon ona.
O tun salaye pe pataki idagbasoke
ajosepo ni lati jo tun ojo iwaju se ni erongba
pelu awon onise aladaani nla ki ipinle ba tun le gbero si, ki ise si wa
fawon ti ko nise lowo.
Gomina Dapo Abiodun tun fikun oro e
pe Ona Eko si Abeokuta je eyi to maa n
banilokanje paapaa lakooko ojo, o ni awon eeyan si maa n lo won si n bo lona
lojoojumo.
O fikun oro e pe "Awon eeyan to n wa lati Iyana Ilogbo maa
n so nnkan toju won n ri lalaal lojoojumo nitori ona to ti baje naa.O ni ona
yii ti won ti n sise lori e tipe si nilo bilionu merindinlogbon naira ki won to
pari e.
"Billionu naira kan nijoba
apapo seto e ninu eto isuna fun ona naa.Gege bi ijoba to sunmo awon eeyan e, to
si n fee nnkan gidi fun won, a ni lati wa nnkan se ",
Bee lo ni ona Epe - Ijebu Ode naa n
fe iru nnkan bee ati ona Ikorodu-Sagamu.
O ni ijoba ipinle Eko ti pari ona ti
won si Epe-Ijebu Ode. Nnkan tawon n fee ni lati se kilomita merinla abo ko fi
le bara won mu.
No comments:
Post a Comment