Owo eso alaabo ti te Arakunrin kan
ti won pe ni Afaa, Moshood Abdul, lori esun pe o ba awon omobinrin kekekee meta
ti won kawe nileewe e sun.
Gege bi Ogbeni Morouf Kolawole Yusuf,
agbenuso feso awon alaabo naa se wi, lojo kin in ni, osu keje, ti se anaa,lowo
te okunrin naa.
Won loun lo nileewe aladaani kan ti
won pe ni Almoqmoon, to wa ni Labori-Oloja, nijoba ibile idagbasoke Sagamu South,
Ogijo.
Awon omo to fipa baa sun naa ni Rukibat
Abubakiri, omo odun mesan, Mutmainat Oladotun, toun naa je omo odun mesan ati Sufiat
Yusuf omo odun mejila.
Yusuf tun so pe Afaa naa ti jewo pe
loooto loun fipa bawon omo naa sun, ati pea won ti fa okunrin naa le awon
olopaa to wa ni Ogijo lowo, ti won si ti bere iwadii kiakia.
No comments:
Post a Comment