Adajo da ebi Akindipo lare lori ile won tawon ajagungbale gba. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 4 July 2019

Adajo da ebi Akindipo lare lori ile won tawon ajagungbale gba.Adajo ileejo giga kerin to wa ni Isabo, niluu Abeokuta ti da ebi Akindipo lare lori ile won tawon ajagungbale gba mo won lowo, bee lo si ni kawon to fi tipa gbale naa san egberun lona aadota lenigba owo itanran fun iya ti won fi je awon to nile naa.

Gege bi idajo kan to waye lonii, ni Adajo Ayanfowokan ti pase ki ajagungbale ti won fesun kan naa, Alaaji Halidu Surakayatu, Arabinrin Sola Dahunsi Fatunbi,  Ogbeni Olanrewaju Lukmaanu Adeogun, Ogbeni Waheed Awolu atawon yooku won kuro lori ile abule Ika-Ajibefun to wa lona Idi- Ori nijoba ibile Abeokuta North naa, nitori awon ko lo nile naa.

Bee lo tun so pe gbogbo itankitan tawon ti won pe lejo naa pa ko lese nile rara, nitori idi eyi ki won kuro lori ile naa, ki won si faa le egbe Akindipo ti won nile naa.

Gege bi Agbejoro ebi naa, Ogbeni Oladepo Onipede, se wi, o ni  inu oun dun fun igbejo naa nitori Adajo to gbejo naa sise e, bo ti to ati bo ti ye.


O so pe teletele ko si ofin kan to de awon ajagungbale tele, idi niyii ti won fi n se nnkan to wu won sugbon oun dupe lowo ijoba ipinle lori bi won se gbe ofin kale pe enikeni to gba gbale onile tabi jagungbale, ewon ni, iyen leyin ti adajo ba so pe o jebi.

Nipa oro ile Ika- Ajibefun ti won gba idalare lori e, Agbejoro Onipede so pe lati nnkan bi odun 2015 lawon ti wa lenu e, tawon Halidu, Sola Dahunsi , Waheed Awolu ti koko folopaa mu awon lee lori.

O ni bawon loruko je ti won si gbe ebi naa loo si kootu sugbon tawon bori ejo naa. Leyin eyi, lo ni awon sese gbe won loo sile ejo giga, ti idajo sese waye lonii, tawon si jare.

O ni Adajo ti da gbogbo itankitan ti won pa nu, o ni ko fesemule. Ni bayii, ti igbejo ti waye, awon ebi Akindipo ti wa ke si awon eeyan lati ma lo ko si owo gbaju e nipa rira ile won lowo awon ti won da lebi naa. Won ni awon ebi naa ti gba ile awon ati pe Alaaji Rilwaan Alao Akindele ni olori ebi naa.

No comments:

Post a Comment

Pages