Latari awon ona kan ti agbara ojo
baje lose to koja niluu Abeokuta, eyi to je kawon agbegbe kan ni Opako/ Adigbe
road nijoba ibile Obafemi Owode denukole, ijoba ipinle Ogun ti gba awon
to ba n gbawon ona yii koja lati sora se, ko ba le dena ijanba moto to le waye
lojiji.
Noimot Salako-Oyedele, to je
igbakeji gomina nipinle naa lo gba awon eeyan naa nimoran lakooko to saaju awon
oga agba nileese to n ri si oro ise ati imayederun sabewo sawon agbegbe naa
pelu ase lati odo Gomina pe kawon to n koja lagbegbe naa gbakiyesi ti won ba
koja.
Igbakeji gomina naa tun so pe"
Idi taa fi wa nibi ni lati ye agbegbe
yii wo, ka si fun Gomina Dapo Abiodun lesi kawon eeyan le kuro ninu ewu ona naa
" Pelu gbogbo abewo taa se, a
rii pe okan lara ipenija ti won koju nibi ni ona titi ti won n gba koja, eyi ti
ko saye fun omi lati gbaa koja lakooko ti ojo ba n ro.
Salako-Oyedele tun fikun oro e pe ona
abayo si wahala to n sele ni lati ona to gbooro fun agbara lati maa koja
lakooko ti ojo ba n ro.
Pelu idaniloju pe ise yoo bere laipe
yii lona kan laidi ona keji pa fawon eeyan lati maa rin, ti ko si ni si isoro
kankan fawon eeyan nigba ti ojo ba n ro.
O wa lo akoko naa lati gba awon
onimoto atawon to n fese rin nimoran lati pa ofin ati ilana mo ti won ba n se
atunse ona naa.
No comments:
Post a Comment