Okan lara agba oselu ni Dokita Femi Majekodunmi, o si ti ko ipa pataki lati je ki isokan ati alaafia joba lorileede yii ati nipinle Ogun. BO SE RI salabapade okunrin yii nibi ti won ti jo forojomitoro oro.
Eto oselu to sese bere nipinle Ogun
Adupe lowo
Olorun bo se ri, nnkankan wa taa n fee lakooko ipolongo, ohun ni pe a fee ki
gbogbo APC wole, a fee ki Buhari wole leekeji gege bi aare, ko lo odun mejo e.
Adura wa naa
nipinle Ogun ni pe a fee Dapo Abiodun wole gege bi gomina, wahala po lori oro
ti Dapo sugbon ope ni fun Olorun to je ki a se aseyori lori e.
A si ti
seleri lagbara Olorun pe Buhari maa se daadaa ju tele lo ni orileede yii, Abiodun
naa maa se daadaa ju eni to wa nibe tele lo, ki awon eeyan wa ko ma mikan.
Awa taa fi
Dapo Abiodun si, a ti mo tipe, emi gan-an ti mo on lati kekere, o je eni to ba
dawo le nnkan to yori si rere gege bi ti gomina se yori si rere lo maa muse.
O si ni eto
fawon araalu, ki i se gbogbo eeyan lo maa gba ipo, eyi to dara ju ni pe ki
alaafia wa ni ilu,ko ma si wahala, kawon to fee jeun ki won le jeun, awon to n
wa ise, ki won ri ise, awon agbe, eleto ilera atawon mii in, ki gbogbo e le maa
lo bo ti to ati bo ti ye.
Dapo Abiodun ko fise fale rara.
Lori awon to
so pe Dapo Abiodun fise fale, haaaa, omo eeyan, osu meji pere lo maa si debe [o
rerin] ko tie ti pe osu meji, osu kan lo sese debe, sugbon ko ye ko ya wa lenu,
iya tawon eeyan wa je, o po loooto.Bii pe ko debe, ko di alalupayida ni, awon
eeyan ko setan lati duro ose kan, awa taa je asaaju egbe oselu, la mo nnkan to
sele, gbogbo awon araalu lo n fe kiakia, ko si eyi to fee duro de gomina gan-an.
Won ti
gbagbe pe gomina funra e gbodo maa seto
lo, won ti seto ileri ko to wole, Olorun si ti gbo adura e o tii wole, a ni
lati fun ni akoko kawon eto to fee maa se, maa lo ni diedie.
Se e gbo pe
ko si owo kankan nibere, se lo loo ya owo lati sanwo awon osise ni, gbogbo
nnkan to ku lo maa se, ka kan fun lakooko lati se ni. Nitori o ni eto daadaa
fawon araalu, suuru ni ki won ni.
Idi ti mo fi sise fegbe oselu ADC
Awon to so
pe mo loo sinu egbe oselu ADC, ko ye won ni, bi e ba ni anfaani lati ka gbogbo
nnkan ti mo so sinu pepa,mi o figba kan kuro ninu egbe APC.
Gbogbo aye
lo mo bi mo se sunmo Baba wa, Obasanjo, mo nifee won, awon naa si nifee mi,
nigba ti ko nife sinu egbe APC mo, Baba lo pe mi pe ki n wa da si oro yii, eni
ti mo si bowo fun ni won.
Baba lo so
pe awon nilo agbari mi, ise ti won fee
ki n bawon se, mo ti se e. Owo ti won koko gbe kale ninu egbe ADC nipinle Ogun,
emi ni eni akoko to gbe owo naa kale.
Leyin igba
yen, Baba Obasanjo tun so pe ki n loo se alaga fegbe naa nipinle Oyo, mo loo,
mo si se e. Mo ranti nigba yen pe mo so fun Gomina Amosun ati Derin Adebiyi to
je alaga APC nigba naa pe mi ko kuro ninu egbe APC ooo, ise ti Baba Obasanjo
ran mi ni mo loo je o, mo n pada bo sinu egbe naa, mo si pada.
Nigba ti mo
rii pe won fee fi iwosi lo mi ninu egbe
ADC, bi mo se pada segbe ti mo wa tele niyen.
Isoro nla ni awon Fulani mu ba wa ni
Nigeria.
Isoro nlanla
ni awon Fulani mu ba wa, to si n da ogun sile laarin North ati South. Awon
fulani yen le pupo eyin naa si mo pe ti oro ba di awon to n deran ninu igbo,
won mo nipa e daadaa.
Gbogbo igbo
Naijiria ni won wa, ti won ba gbe ogun ti wa tabi tawa gbogun ti won, wahala
ni.Eyin naa e wo iru itu tawon Boko Haram, ija gorila ni, won soro lati bori.
Idi si ni pe
awon olopaa, soja wa, won ko ko won bi won se le ja ninu igbo, ija inu igbo die
ni won mo nipa e sugbon awon fulani won mo nipa e daadaa.Won tun nija oloro
lowo yoo si soro fun ijoba kan lati doju ija ko won.
Ifaseyin to de ba oro aje ipinle
Ogun, ebi gbogbo wa ni
Lero temi,
ebi gbogbo wa ni ifaseyin to de ba oro aje nipinle Ogun iyen ni mo se maa n so pe
ka gbadura daadaa ki Olorun fun wa ni asaaju rere, ti won ko ni maa huwa ibaje,
ti won yoo je apere rere fawon to n bo.
Ohun to si tun
le tan isoro ni ti gbogbo wa ba fimo sokan, ka wa ni alaafia, a n fee asaaju
rere ti won setan lati fa ara won sile, ki gbogbo nnkan le maa lo deedee.Nitori
gbogbo olori wa ija ara won ni won n ja, bi won yoo se toju ara won, ti won yoo
toju molebi ni won n wa.
Ko si nnkan
tawon oloyinbo pe ni Loyality, iyen kaa nifee ilu ni orileede yii. Bi joba se
nipa ninu ifaseyin to de ba wa nipinle Ogun bee lawa araalu naa nipa.
Nitori e ni
mo se so pe a ko nii awon asaaju rere, a fi ta ba ni olori daadaa nikan lo le
mu wahala yii kuro yala lori owo ori ni,
ina ni atawon nnkan mii in.
Ko soro fun
wa lorileede yii lati wa ni ifokanbale iyen taa ba ni okan isokan. Gbogbo wa la
n ranti Awolowo, kin ni o se nigba naa, letoleto lo se awon nnkan nigba naa.Awon ise to se
sile si wa ti ko baje titi di oni yii.
Idi ti mi o fi tele oro Obasanjo nipa
APC
Se e ri ki
eeyan je olooto si eeyan tun yato si eto, to ba finu tan eeyan iyen ko ni
konitohun maa se nnkan to ba wuu,lokan temi APC ko semi, bi won ba tie se
araalu, a o beere ona ti won gba se won, ki won si yanju e.Oselu ni nnkan to n
so yen, Baba lo maa mo idi ti won fi fee PDP, awon naa lo si maa mo idi ti won
ko fi feran APC, o yato si temi, e e ma je ka so ju bee lo.
Ipa ti mo ko ninu egbe oselu nigba ti
mo pada de APC
Awon ipa ti
mo ko ko lonka, wahala ti mo koko koju ni pe lati pari ija laarin Amosun ati
Dapo Abiodun, mo so fun Amosun pe ti Dapo Abiodun ba see, ko dariji, ti APC naa
lo ba si se e ko dariji. Ko gba Dapo Abiodun gege bi oludije, mo se wahala
gan-an lee lori.
Dapo ko tie ri ti Amosun roo pelu gbogbo nnkan
ti gomina tele naa se fun un, ko janpata rara, titi di akoko yii naa, e o le ri
ko soro. Gbogbo nnkan to si sele si Amosun ni mo tii so fun pe o maa sele.
No comments:
Post a Comment