Gomina Dapo Abiodun tipinle Ogun, ti
so pe ala ti ko le se ni ki awon to mule ti orileede wa legbe gba Tongeji, eyi to
je aala laarin Naijiria ati orileede Benin mo won lowo lakooko isejoba e.
Pelu ileri pe gbogbo ona nijoba e
yoo sa lati rii pe igbe aye irorun je tawon omo ipinle naa to wa lagbegbe naa.
Gomina soro yii lakooko to n gba alejo asoju ile wa ni orileede Benin
Emmanuel Kayode Oguntuase ati oga ologun Oladele Daji.
O so pe iriajo asoju ile wa
lorileede Benin yii yoo je ki ijoba e tete bere igbese lati ma je ki orileede
Benin lo anfaani to wa lagbegbe ijoba ibile Ipokia lati gba mo won lowo.
Ati pe ijoba e yoo gbe igbimo kan
dide laipe yii ti yoo sabewo si Tongeji naa lati mo nnkan ti won le se tawon to
n gbe nibe ko nii fi deni igbagbe.
Gomina Abiodun tun fikun oro e pe isakoso e ti je kileese
ijoba apapo to n ri si epo petiroolu mo pe agbegbe naa je ibi tawon fokan si
lati le mu owo jade ati pe awon ti n ba olokoowo soro lati wa nnkan ti won le
se si.
Bee lo ni ijoba e ko tun ni foro
awon eeyan to n gbe lagbegbe naa fale lati mo nnkan ti won tun le se fun won
pelu ileri pe oun yoo gbe ejo won lo si ajo to n ri si aala iyen National
Borders Commission.
Abiodun wa dupe lowo Oga ologun Oladele Daji lori bi ko se je ki wahala sele lagbegbe bee lo wa gba a
lamoran lati ri pe eto abo to peye wa.
Ninu oro ti asoju ile wa lorileede
Benin, Emmanuel Kayode Oguntuase, so pe idi toun fi sabewo wa sodo gomina ni
lati mo nnkan to n sele lagbegbe Tongeji.
Bee lo ni o se pataki lati je ki
Gomina mo ipa tawon to wa ni orileede Benin n sa lati gba agbegbe naa mo won
lowo nitori epo petiroolu ti won ri nibe.
No comments:
Post a Comment