Dapo Abiodun fidi egbe oselu Labour janle nileejo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 13 July 2019

Dapo Abiodun fidi egbe oselu Labour janle nileejo




Igbimo to n gbejo lori awyewuye to sele lakooko idibo gomina to waye ninu osu keta ti fidi egbe oselu Labour janle nigba ti won wogi le ejo ti won pe Gomina Dapo Abiodun.

Nibi igbejo to waye lojo Abameta, Satide, ni Adajo Yusuf Halidu, to je olori igbimo to n gbejo naa ti wogi le ejo ti nomba e je EPT/OG/GOV/03/2019 laarin Atabinrin Modupe Sanyaolu, tegbe oselu Labour ati Dapo Abiodun, tegbe APC ati ajo INEC.

Gege bi Adajo naa se wi, won ni awon wogi le ejo tegbe oselu Labour pe gege bi ofin ati ilana  ti lori bi awon olupejo se kuna lati wa soro lori ejo ti won pe.

Adajo Halilu wa so pe ejo ti won pe naa ko lese nile, nitori bi won se saa nileejo lakooko to ye ki won wa rojo.

 Ninu oro Wale Habeeb Ajayi, to je agbejoro fun Gomina Dapo Abiodun, O ni ejo naa ti ku sona. O ni egbe oselu Labour ti won kuna lati fi oruko oludije igbakeji gomina sile fun ajo INEC, bee lo tun ni won ko lati ke gbajare sita ki ibo to waye, ti won ko si pe ajo eleto idibo lejo ki ibo to bere ni won wa sese wa gbejo wa siwaju awon to n dajo.


Bee lo ni awon eeyan naa tun kuna lati wa siwaju adajo lawon ojo ti won pe fun igbejo. O wa ni igbese gidi lawon to n gbejo naa gbe lati fagile e nitori awon to pejo naa bigba ti won fakoko sofo ni.


No comments:

Post a Comment

Pages