Egbe apapo oselu ti won foruko sile fun ibo to waye seyin ti ro oludije fun ipo gomina labe egbe oselu APM, Onarebu Adekunle Akinlade, lati jawo ninu ejo ti okunrin naa pe Gomina Dapo Abiodun, lori ibo gomina to waye ninu osu keta.
Oro yii waye ninu ipade
oniroyin ti apapo egbe oselu naa pe nibi tawon to dije fun ipo gomina labe egbe
oselu kookan ti ro Akinlade lati gba kadara gege bawon naa se gbaa, ko si gba
lati baa sise papo.
Ninu oro Adebayo Mosuro so
loruko awon oludije gomina yooku lo ti so pe awon ro Akinlade lati jawo ninu
ejo to pe Dapo Abiodun, ko si ki i ku oriire gege bawon oludije yooku se se
Awon apapo egbe oselu naa ti
won to mejidinlogoji, ti won ni oludije gomina meedogun ni won tun so pe ko tii
pe ju ti Akinlade ba jawo ninu ejo naa, ti ki i ba se pe imotara eni nikan tabi
ife ara e lo n le.
Mosuro tun so pe ki Akinlade
gba kamu bi Gboyega Isiaka tegbe oselu ADC, Buruji Kashamu egbe PDP,
Rotimi Paseda ti SDP ati Sina Kawonise ti YES se se ti won gba abajade
esi ibo naa.
Okunrin naa tun so pe gbogbo
awon egbe oselu naa lo gba pe ibo naa waye nirorun rose. O so pe ejo ti APM pe
lakooko yii ko nitumo bigba teeyan fakoko sofo ni.
Bee lo tun ro igun mejeeji
egbe oselu Lebo naa lati jawo ninu ejo tawon naa pe Dapo Abiodun.
No comments:
Post a Comment