Lori oro kan to n loo nigboro pe Oloye Gbenga Ogunwale, topo mo si ese mefa, okan lara awon to n dije fun ipo alaga fegbe awon onikeke elese meta iyen Three Wheeler Owners and Riders Association ( TWORA), pe o n wona lati da wahala sile ninu egbe naa lati fi tako igbese ijoba, okunrin naa ti so pe ko si ooto ninu e, won kan fee fi ba oun loruko je ni.
Okunrin naa so pe iro nla ni esun
naa ati pe awon ota oun lo n sise naa, nitori ki won fi da nnkan ru mo oun loju
ni sugbon Olorun ko nii gba fun won.
Ese mefa tun fikun oro e nipa fifi
esun kan enikan to n je Ismail Olanrewaju Yusuf, tawon kan n pe ni Mayasau, to
ni o je osise fegbe oselu APM, toun naa fee dije fun ipo alaga TWORA pe oun lo
fee da wahala sile to n paro mo oun.
Ogunwala tun salaye pe oun ko le
tako ase ijoba laelae, nitori eni to n bowo fun ofin ati ilana ile wa loun. O
ni oun ko le da wahala sile depodepo pe oun yoo gbimo e ninu egbe naa, o ni
awon igbimo ti won sagbekale e ti se
ipade po pelu awon lori ona tawon le gba maa fi sise fun odidi osu meta..
O ni won fee ba oruko toun ti ni je
ni sugbon Olorun ko nii gba fun won. O wa seleri atileyin e fun igbimo tijoba
ipinle Ogun sagbekale e.
No comments:
Post a Comment