Ori ko Idowu Adenekan, Oluwo onitiata yo ninu ijamba moto - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 21 July 2019

Ori ko Idowu Adenekan, Oluwo onitiata yo ninu ijamba moto



Bi ki i ba se opelope Olorun, oto ni nnkan taa ba maa so nipa agba osere onitiata nni Idowu Adenekan, topo awon eeyan mo si Oluwo, nitori bi ori se ko o yo ninu ijamba moto kan to waye.

Okunrin naa to n se ifilole fiimu tuntun ti akole e n je Eewo lonii in la gbo pe ori ko yo ninu ijamba moto kan to waye Lojoruu, Wesidee, ose taa lo tan yii lagbegbe Makun, loju ona marose Eko si Ibadan.

Ni nnkan bii aago meta osan ni ijamba naa waye, Gege bi osere  naa se wi, o ni ibi ipade kan lawon loo fun ti ayeye ifilole fiimu to n se lonii yii.

O ni bawon se de agbegbe ibi ti ijamba naa waye, o ni lojiji  lawon rii pe moto moto ohun bere sin ii pidan, kawon si to mo nnkan to sele, moto naa ti fee loo ko seyin tirela to si ti wo.

Agba osere onitiata tun salaye pe oun ko le so pe pato nnkan bayii ni o fa ijamba moto naa ati pe bo ti sele tan, ekun lo ni Ogbeni Tajudeen Olanrewaju to wa moto naa n sun pe moto ti baje.

O fikun oro e pe oro oun to ope, o si ju ope loo nitori pe ka ni dereba ohun look u sinu ijamba naa ni oto ni nnkan tawon eeyan ko ba maa so.

Paapaa to je pe ipa Babalawo toun maa n ko ninu fiimu sugbon oun dupe pe ayo lo gbeyin e, nitori awon eeyan to wa nibi ifilole toun se, won ko wa ba oun kedun laburu ati pe nnkan ti won yoo fi sun ifilole naa siwaju Olorun ko je ko sele.

No comments:

Post a Comment

Pages